*Ìwà rere*
Iléere ní ẹ̀ṣọ́ nínú
Ìwà’bàjé ní jẹ́ k’ọ́mọ o j’ìyà
Ẹwúrẹ́ ya aláìgboràn
Àgùntàn jẹ́ oníwàpẹ̀lẹ́
Adígbánnákú ṣẹ̀yìn gákangàkan
Iléere ní ẹ̀ṣọ́ nínú
Ìwà rere lẹ̀sọ́ ènìyàn
Ìwà rere ni òbí ní,
tí wọ́n fi ń ǹpé ní òbí rere
Òbí rere ló le kọ́mọ ní’wà rere
Òbí rere ní fi ìwà rere kọ́ni
Ìwà rere kọjá ẹ̀sìn
Ẹ̀sìn bá ìwà rere láyé ni
Kíì ṣe ẹ̀sìn ní kọ́ni níwà rere
Ìwà rere ni ẹ̀sọ́ ènìyàn
Ìpáǹle kìí ṣe ìwà tó tọ́
Àigbọ̀ràn kìí ṣè’wà rere
Agbójúlógun firarẹ̀ fóṣì ta
Ká-tẹ-pá mọ́ ‘ṣẹ́ ohun pẹ̀lú ìwà
Ojúkòkòrò kìí ṣèwà ire
Ìwà rere dántọ́, ó tayọ, ó yàtọ̀,
Ìwà rere ní àpọ́nlé
Óń buyì kún ní
Óń fi ni hàn lọ́nà tó gún
Óń kóni yọ nínú ewu
Ká tọ́ jú ìwà to pé, tó tọ́
Gbogbo èèyàn ló dá ọmọluàbí mọ̀
Èéfín nìwà
Ìwà kò ́ṣèe kó pamọ́ sínú ǹkankan
Ìwà kò ṣeé bò mọ́lẹ̀ bí èbù iṣu
Ìwà ma ń ru sókè láìrò
Tọ́jú ìwà rẹ ọ̀rẹ́ mìi
Kí tẹrú tọmọ lè pọ́n ọ lé
Ìwà rere ǹgbèni débi ayọ̀
Ẹní bá níwà ní jọlá, ẹní bá níwà níí jọlà
Ẹníbà níwà ní jère ire
Tọ́jú ìwà rẹ ọ̀rẹ́ mìi
Ìwà rere lẹ̀ṣọ́ ènìyàn.
*Ẹdaọtọ Agbeniyi*
Lagos, Nigeria.