Otun Olubadan ti ile Ibadan, to tun je okan pataki ninu awon agba oye ile Ibadan, Omowale Kuye, ti dagbere faye leni odun metadinlaadorun (87). Oloye yii la gbo wi pe o dake ninu ile re to wa ni agbegbe Ikolaba to wa niluu Ibadan ni nnkan bi ago meje abo ale Ojobo ose to koja yii. Titi di akoko ti a fi n ko iroyin yii, awon ebi oloye naa ko ti kede ohun to sokunfa isale naa.
Ojo kejidinlogun osu kewaa odun 1928 ni won bi Oloye Omowale Ajani Kuye. O si kaye gboye nipa eto oro-aje (Economics) ni University of London lodun 1963. University of Syracuse to wa ni ilu New York, Amerika lo ti gboye eleekeji. Leyin eyi lo tun lo ka nipa imo ofin ni Nigeria Law School lodun 1978.
Aimoye eka ile ise ijoba ni Oloye Omowale ti sise ko to wa di wi pe o feyinti lodun 1988.
Aimoye eka ile ise ijoba ni Oloye Omowale ti sise ko to wa di wi pe o feyinti lodun 1988.