Home / Art / Àṣà Oòduà / A DÚPẸ́ OOO GBOGBO ILẸ̀ WA TI DI IBOJÌ

A DÚPẸ́ OOO GBOGBO ILẸ̀ WA TI DI IBOJÌ

A dúpẹ́ o
Ikú ti di tiwa
A dúpẹ́ o
Àwọn èèyàn wa ò figi da mààlúù mọ́
AK 47 ni wọ́n ń lò
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run
Iṣẹ́ darandaran ti di iṣẹ́ dánràndáràn
Èdùmàrè a dúpẹ́ o

Ẹ dúró ná
Kí loun tá a ṣe
Tí gbogbo ilé wa kún fún ikú
Tí gbogbo Ọ̀dẹ̀dẹ̀ wa kún fún àrùn
Àwọn ẹranko tí ń bẹ nínú igbó ń gbádùn ayé jù wá lọ
Èdùmàrè
Kí loun tó ń happen ná
Áńgẹ́lì tó ń pín ikú
Kí ló dé tó jẹ́ pé o kò lọ sórílẹ̀ èdè mìíràn mọ́

Ẹ wo òkú ọmọde lójú u pópó
Ẹ wo òkú àgbàlagbà lẹ́ṣẹ̀ ọ̀nà
Ẹ wo òkú ọmọge tó ti di wúńdíá
Ẹ wo tàwọn ọ̀dọ́ tó ti bàlágà
Ọmú abiyamọ kò yọ omi mọ́
Ikú ti gbọ́mú lọ

Èdùmàrè
Ayé ti apá ibi yìí kò suwọ́n
Àwa ènìyàn ìhín kò dára
Wọ́n ń pa wá
Wọ́n tún ń dúró ti wà
Ojoojúmọ́ lẹran ara wa ń wọlẹ̀

Èwo tún lèyí ooo
Olódùmarè!!!
Ṣàánú ooo
Kò sílẹ̀ tá a fẹẹ gbinsu sí mọ́
Gbogbo rẹ̀ la ti sìnkú sí ooo
Ọlọ́run Ọba Aláṣẹ
Èdùmàrè ọba asẹ̀dá
Dákun
Bá Nàìjíríà lálejò
Jẹ́ ká yéé dúpẹ́ túláàsì…

Ẹ̀JẸ̀ ÒKÚ Ń SUNKÚN OOO

Láti owó Africulturist Femi Ajakaye

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

taniolohun

Esin Ajeji Pelu Ete