Home / Art / Àṣà Oòduà / A kú àmójúbà *Oṣù Ògún (August) tuntun.* Oṣù ìdùnnú ni yóò jẹ́ láṣẹ Èdùmàrè

A kú àmójúbà *Oṣù Ògún (August) tuntun.* Oṣù ìdùnnú ni yóò jẹ́ láṣẹ Èdùmàrè

A kú àmójúbà *Oṣù Ògún (August) tuntun.* Oṣù ìdùnnú ni yóò jẹ́ láṣẹ Èdùmàrè. Gbogbo àdáwọ́lé wa ló máa yọrí sí rere. Aboyún ilé á bí wẹ́rẹ́, àgàn á tọwọ́ àlà bọ osùn. Gbogbo ẹni tó ń ṣòwò yó jèrè, wọ́n á bóde pàdé, bẹ́ẹ̀ wọn kò níí pàdánù. Oṣù Ajé suurusu ni yóò jẹ́ ó..

_Ogún lewé Ìná_
_Òjì ni ti Ìrókò_
_Àádọ́ta ni ti Mìnìrọ_
_A dífá fún Ọlọmọ tí yó ṣòwò_
_A dífá fún Ọlọmọ tí yó jèrè_
_A dífá fún Ọlọmọ tí yó forí ara rẹ̀ kérè délé_
_Òwèèrè lọjà_
_Ifá jẹ́ n kérè délé kokoko…_

Èrè ni ọlọ́jà ń jẹ, gbogbo wa ni a ó forí ara wa kérè délé ooo.

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti