Home / Art / Àṣà Oòduà / Akékòó okùnrin tí ó ti wà ní ìpelè tí ó parí ní ilé-èkó gíga polytechnic ti ìlú Oko ni won yìnbo fún tí ó sì kú.

Akékòó okùnrin tí ó ti wà ní ìpelè tí ó parí ní ilé-èkó gíga polytechnic ti ìlú Oko ni won yìnbo fún tí ó sì kú.

Arákùnrin kan ni won yìn ìbon fún ní ilé-èkó gíga polytechnic ti ìjoba ní Oko ní ìpínlè Anambra.

Gégé bí ìròyìn se so, olóògbé tí gbogbo èèyàn mò sí ‘ De moon’ jé Akékòó féè pari tí ó sì jé wípé odún yí ni yóò parí èkó rè, ni won ti yin ìbon fún ní alé ojóbò (Thursday) tí se àná. Agbó wípé eka-èkó Banking and Finance ni ó wà ní ilé-èkó náà.
Àwon akékòó tí ó n gbé ní inú ogbà yí ti è ti ñ bèrú tèlè kí ó tó di wípé èyí tún selè.
Ìdí tí ó fa ìbon kò tí yé eni kankan, bí àwon kan se so wípé àwon omo egbe òkùnkùn ni ó yin ìbon náà, tí àwon kan sì so wípé olóògbé n ló èro ìbánisòrò rè mó àwon tí ó yìnbo yí lówó kí won tó paá.
Ìsèlè yí ti kó jìnìjìnì bá òpò akékòó.

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti