Araba Yemi Elebuibon and Iwarefa Praying for Peace & Prosperity for Nigeria and Worldwide.
Ẹlẹ́buùbọn gba ìpàdé àwọn ẹlẹyẹ ẹ̀ka ti Ọ̀ṣun Fẹ́mi Akínṣọlá Gbajúgbajà onímọ̀ nípa ìṣègùn ìbílẹ̀ nílẹ̀ ẹ Yorùbá, tó tún jẹ́ Olóyè Àràbà nípìńlẹ̀ Oṣun. Ifáyemí Ẹlẹ́buùbọn ti gba ìpàdé ńlá àjọ̀dún ayẹyẹ àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn oṣó àti àjẹ́ ní ìpínlẹ̀ Oṣun. Níbi ìpàdé yìí ni onímọ̀ ìṣègùn ìbílẹ̀ ti fi ọ̀rọ̀ léde pé ìtàjẹ̀sílẹ̀ léwu púpọ̀ fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè yìí. Nígbà tó ń bá ìpéjọpọ̀ náà ṣọ̀rọ̀ lọ́jọ́bọ ọse, èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ ti ẹgbẹ́ ìtẹ̀síwájú ...