Home / Art / Àṣà Oòduà / Atelewo eni ki i tanni i je
Wole soyinka

Atelewo eni ki i tanni i je

Awon Yoruba bo, won ni amukun-un eru re wo, o ni oke le n wo, e wole. Ojuse awon obi ki i se lati pese ohun ti awon omo won ba n fe nikan, bikose lati sakiyesi iru ebun ti won ni ati ona ti won le gba ran won lowo lati pese won sile fun ojo ola. Sugbon ohun to joniloju ni wi pe pupo awon obi ni ko tile raaye fun awon omo won rara.

Mo ti so saaju ni abala yii wi pe isoro kan pataki ti awon eniyan n koju ni ona ati sawari ebun won ati ona ti won le gba lo ebun naa fun igbega ara awon.

E je ka mu lokookan-ejeeji. Lakoko na, awon eniyan maa n foju reena awon nnkan pataki to jeyo jade ninu iseda won latari wi pe iru awon nnkan bee ko jo won loju. Sugbon ohun ti won ko mo ni wi pe pupo awon nnkan bayii ti won ko kakun ni ko wopo ninu iseda awon eniyan to wa layika won.
Ohun kan ti mo tun sakiyesi ni wi pe, talenti ti eniyan ni, nigba mi-in, a maa farasin sinu nnkan mi-in ti ko jo ebun rara nibere pepe.

Gege bi apeere, orisii awon eniyan kan wa ti won feran pipalemo nigbogbo igba. Opolopo le ma ri eleyii gege bi ebun kan pataki. Sugbon iru awon nnkan bayii maa n se apejuwe iru ebun to seese ki iru eni bee ni. Elomii korira lati foju ri idoti kekere nigba ti awon kan ki i kuna ninu igbaradi tabi imurasile de ohunkohun to ba wa niwaju won. Oro oloro a ma ka elomii lara gan-an, paapa ju lo to ba ni i se pelu iyanje.

Awon kan feran lati maa fi ara won sile fun ise egbe, adugbo, agbegbe tabi ilu. Awon kan ni ebun agbekale oro siso tabi alaye to gunrege, awon kan ni suuru bakan naa ni won si maa n mo oro gbo pelu ifarabale.

Sugbon nitori wi pe a ko kiyesi iru awon nnkan wonyii gege bi ebun pataki, pupo won ni ko yori si ebun nla fun wa. Pupo awon eniyan ti won feran ki n nnkan maa wa letoleto nigbogbo igba, yala ninu ile won, tabi awon ohun ini won ni won maa lebun isakoso. Pupo iru awon eniyan bayii ma n jijadu lati wa nidi eto nigbakuugba ti anfaani re bayo laaarin awujo. Won si ma n fe lati fi ara won sile fun ise ilu.

Bakan naa, awon mi-in feran okoowo sise, isiro ki i ro won loju. Bi owo won ba wa lowo onigbese won, won mo ogbon ti won fi le gba iru owo bee pada.

Ki i se gbogbo eniyan lo le se eleyii nitori wi pe o ni i se pelu ebun onikaluku. Ejo riro, oro siso ro awon mi-in lorun to je wi pe won le soro lataaro dale. Awon elomii feran imo, won si feran lati maa kawe gan-an lopo igba. Awon nnkan bayii, ati awon mi-in lo n se afihan, itoka tabi ibere orisii ebun ti eda eniyan ni. Sugbon nikete ti a ko ba ti se akiyesi won ni won ko ti ni itunmo mo. O si daju wi pe won ko ni se e lo fun wa.

E je ki a ma sakiyesi awon ohun ti owo wa maa n ya si tabi ohun ti maa n ya wa lara lati se nigbogbo igba. Bi won ko tile foju jo ebun kan to joju, e je ka maa wo sakun ohun to le bi, ati ona to le gba wulo fun wa. Iru ona wo ni a le gba tabi iru ise wo ni a le muse ti iru awon nnkan ti a sakiyesi yii yoo fi je bi iranwo fun wa?

 

Olayemioniroyin.com

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

prof wole soyinka

Professor Olúwọlé Ṣóyínká Turns 90th Today

Akinwande Oluwole Babatunde “Wole” Soyinka CFR  Akínwándé Olúwọlé Babátúndé “Wọlé” Ṣóyínká,  born 13 July 1934) is a Nigerian playwright, novelist, poet, and essayist in the English language. He was awarded the 1986 Nobel Prize in Literature for his “wide cultural perspective and… poetic overtones fashioning the drama of existence”, the first sub-Saharan African to win the Prize in literature. Olúwọlé Ṣóyínká’s Early life Soyinka was born into a Yoruba family in Abeokuta, Nigeria. In 1954, he attended Government College in Ibadan, and subsequently University College Ibadan and ...