Home / News From Nigeria / Breaking News / Àwo̩n aronúpìwàda Boko Haram ké̩kò̩ó̩ parí

Àwo̩n aronúpìwàda Boko Haram ké̩kò̩ó̩ parí

Ìjọba ṣetán láti ra irinṣẹ́, sanwó oṣù fún adúnkookò mọ́ni tẹ́lẹ̀

Àwọn ikọ̀ agbésùnmọ̀mí tó to mọkanlelẹgbẹta ti wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún ìjọba, ti kẹ́kọ́ọ̀ jáde nílé ẹ̀kọ́ .

Ìjọba sì ti setán láti má a san owó ìrànwọ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún Náírà fún wọn ní osoosù, tí wọn yóó sì pèsè irinṣẹ́ fún wọn.

Kọmíṣọ́nnà fún ọ̀rọ̀ ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Borno, Babakura Jatau ló sọ èyí, lásìkò ifọrọwanilẹnuwo kan.

Jatau sọ pé, àjọ tó ń rí sí ìdàgbàsókè ẹkùn àríwá Nàìjíríà, (North East Development Commission) àti Àjọ tó ń rí sí àkóso lílọ-bíbọ̀ èrò láti agbègbè kan sí òmíràn, (International Organisation for Migration) ló fi ìrànwọ́ náà ṣọwọ́ sí àwọn ikọ̀ Boko Haram tó ronúpìwàdà náà.

Ó ní kò sí òtítọ́ nínú ìròyìn pé, ìjọba ń fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ní N100,000, wí pé N20,000 ni àwọn ń san fún wọn.

Bákan náà ni wọ́n fikún-un pé, kìí ṣe gbogbo wọn ni ikọ̀ Boko Haram, àmọ́ lára wọn jẹ́ àwọn tí wọ́n jígbé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, tí wọ́n sì kàn án nípá fún wọn, láti má a bá wọn jalè.

Kọmísánà fún ètò ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Borno, Babakura Jatau ní, láti ìpínlẹ̀ Gombe ni ìjọba yóó ti kó wọn wá sí ìpínlẹ̀ Borno, tí wọn yóó sì kó wọn sí ibùgbé tí wọn yóó ti má a gba ìdánilẹ́kọ́ọ̀.

‘Won yóó má a lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n gbà ní ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n lọ, láti fi ṣiṣẹ́.’

Olú ìlú iléeṣẹ́ ikọ aláàbò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló fi léde pé, ikọ Boko Haram tó lé ní ẹgbẹ̀ta ló ti jọ̀wọ́ ara wọn, tí wọ́n sì ti setán láti darapọ̀ mọ́ àwùjọ.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Isis Released Footage Of Recent Attacks On Government Forces, Civilians In Nigeria

ISIS news agency, Amaq, has released footage of several recent attacks that targeted government forces and civilians in different parts of Nigerian. On July 7, ISIS cells ambushed a convoy of the Nigerian Armed Forces (NAF) on a road between the towns of Dikwa and Luma in the northeastern state of Borno. Four Nigerian service members were allegedly killed. ISIS terrorists also attacked a base of the NAF in the town of Lasa in Borno. According to Amaq, a number ...