Dókítà tí ó ń wo àìsàn tí ó je mó èyà ara omo bíbí (Gynecologist) Dr. Uche Ene, ti gba àwon òdó ní ìmòràn kí won yàgò fún ìbálòpò tí kò ní ìdábòbò kí won má ba kó Àtòsí (gonorrhea) láti ní ìlera tó péye àti láti ní ànfààní àti le bímo pò si.
Ene, adarí ètò ìlera Enugu télè (former Director for public health) gbà wón ní ìmòràn nínú ìfòròwánilénuwò tí ó ní pèlú àwon oníròyìn (NAN) ní Enugu ní ojó ìségun (Tuesday).
Ó so wípé ó ń koni lómi inú ònà tí àwon òdó ń gbà b’ára won l’ájosepo láì lo ìdábòbò ní orílè èdè yí, ó jé kí òpò kó àìsàn Àtòsí (gonorrhea).
Ó so síwájú si wípé àìsàn yí le fa àìle r’ómo bí tí a kò bá tètè mójú to nígbà tí ó bá sèsè bèrè.
Ene so wípé won le tójú rè tí eni tí ó ní àìsàn náà bá le y’ojú sí ilé-ìwòsàn tí ó sì yàgò fún ìtójú ara eni fún ara eni, tí o bá ń tójú ara re ó le fa wàhálà sí aláìsàn l’ára..
Ó tè síwájú wípé kí àwon òdó yera fún ìbálòpò títí won ma fi se ìgbéyàwó, ó so wípé tí won kò bá le dúró de ìgbéyàwó (condom).
Gégé bí ó se so. Àtòsí jé àrùn tí èèyàn máa ń látàrí ìbálòpò tí Bacterium Neisseria gonorrhea máa ń fà, tí ó máa ń fa kí ara ma ló wóóró àti kí ó ma tutù.
Ó tún so wípé àrùn náà le wo ara ènìyàn nípa bíbá ara eni lò pò láì lo ìdábòbò àti àwon tí won bá òpò ènìyàn lò pò…
Continue after the page break for English Version