Home / Art / Àṣà Oòduà / Chimamanda Adichie se ayeye ojó-ìbí rè nígbà tí ó pé omo odún mókànlélógójì (41) lóòní.

Chimamanda Adichie se ayeye ojó-ìbí rè nígbà tí ó pé omo odún mókànlélógójì (41) lóòní.

Chimamanda Ngozi Adichie ni won bí ní ojó keèdógún osù kesàn-án odún 1977 (15/09/1977), jé olùkòwé ní orílè èdè Nìjíríà, ó n ko ìtàn kékeré àti èyí tí ó pò, ó n ko èyí tí ó jé ìtàn ojú gbangban àti èyí tí ó jé àròko tí yóò seni ní ànfààní. Orísirísi ìtàn ni ó ti ko, bí àpeere, purple Hibiscus ní odún (2003), Half of a yellow sun ní odún (2006), àti Americanah ní odún (2013) àti àwon ìtan àròko kékèké náà, bí àpeere, Thing Around your Neck ní odún (2009) àti ìwé tí ó ko wípé ó ye kí gbogbo wa jé a jà fún ètó omobìrin, We Should All Be Feminists ní odún (2014).
Ní odún 2018, Adichie gba àmì èye a MacArthur Genius Grant. Tí won si pon lé, won tún so wípé ohun ni a kò bá ma pè ni oní ìgbà gbogbo àti à fi èbùn lítírésò so èdùn okàn dúnìyàn láti jé kí òpò níìfé lítírésò ní àkókò tí a wà yí. Lára àwon ìwé tí ó sèsè se ni, Dear Ijeawele tabí A jà fún ètó omobìnrin tí a mò sí a Feminist Manifesto in Fifteen suggestion tí won gbé jáde ní odún (2017).

Igba odún, odún kan ni o.

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

orisa

The World of the Yoruba Orisa