Èàkàn ẹgbẹ́ òṣèlú APC mií Lanre Rasak dágbére fáyé
Èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú APC nípìńlẹ̀ Èkó, Lanre Razak ti jáde láyé lẹ́ni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́rin.
Kí ikú ó pajú èèyàn dé lójijì ti wá fẹ́ ẹ̀ kúrò ní ń tí wọ́n kíìyàn yàn pé Ọlọ́run má jẹ́ á rírú ẹ̀ mọ́, bí ó se pé ká sá maa sọ fún Ọlọ́run pé kọ́dún ó jìnà síra wọn.
Ìṣẹ́jú ìṣẹ́jú sáà ni ẹ̀mí ń bọ́ lára gbogbo n tí Aláwùràbí dá, tèèyàn ló kàn wá jù ,la ṣe ń gbarata.
Ọkàn pàtàkì tún ni ti
Ọ̀gbẹ́ni Lanre Razak yìí tó papòdà lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹjọ ọdún 2020 yìí ,lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́.
Nígbà ayé rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Razak wà nínú Ìgbìmọ̀ tó ń gba Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó lámọ̀ràn.
Ọ̀gbẹ́ni Rasak kọ́kọ́ fi èròńgbà rẹ̀ hàn láti díje fún ipò Sẹ́nétọ̀í lẹ́kùn ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ Èkó kí ó tó yọwọ́ níbẹ̀ ṣaájú ìbò abẹ́lé.
Ọjọ́ Àìkú ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹjọ yìí ni wọn yóó ṣin Ọ̀gbẹ́ni Rasak ní Ìlànà ẹ̀ṣìn mùsùlùmí.
Fẹ́mi Akínṣọlá