Èèmọ̀ rè é o !, Ìyàwó àfẹ́sọ́nà kú sínú Kànga, nígbeyàwó kọ̀la
Fẹ́mi Akínṣọlá
À fi ká kún f’áàdúà kí ọjọ́ ayọ̀ ẹni ó má padà dọjọ́ ìbànújẹ́.Kí èṣù ó sì má ráàyè gbọjọ́ ẹ̀yẹ ẹni . À bí kín ni ká ti pe ti ọ̀dọ́mọbìnrin ọmọ ọdún mérìndínlógún kan, Fatima Abubakar tó pàdánú ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tó ré sínú kànga omi nígbà tí ìgbéyàwó rẹ̀ ku ọ̀la.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà la gbọ́ pé ó wáyé ní ìlú Gajaja, ìjọba ìbílẹ̀ Danbatta, nìpínlẹ̀ Kano.
Bàbá Fatima, Ọ̀gbẹ́ni Abubakar sọ fún akọ̀ròyìn pé, ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́gbárímú náà wáyé lásìkò tí ọmọbìnrin náà àti àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ ń lọ fún ayẹyẹ alẹ́ omidan nílé àǹtí rẹ̀ kan l’ọ́jọ́rùú.
“Ń ṣe ló dúró l’ẹ́gbẹ̀ ẹ́ kànga náà, kó tó di pé ó fi ẹ̀sẹ̀ kọ, tó sì ṣubú sínú kànga.
Ọjọ́ kejì, tó jẹ́ Ọjọ́bọ ló yẹ kí ayẹyẹ ìgbéyàwó láàrin òun àti ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ ó wáyé.
Bàbá Fatima ṣàlàyé pé, inú ọmọ òun dùn sí ìgbéyàwó náà, àti pé Ifẹ̀ wà láàrin òun àti ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀.
Ó sọ pé ó ṣeni láànú pé inú ìbànújẹ́ ni àwọn àlejò tó yẹ kó wá bá òun yọ̀ ayọ̀ ìgbéyàwó ọmọ òun wà báyìí.
Inú ìbànújẹ́ ni ọkọ àfẹ́sọ́nà náà wà, tí kò sì le bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀.