Home / Art / Àṣà Oòduà / Eríwo Yà! Eríwo Yà!! Eríwo Yà!!!

Eríwo Yà! Eríwo Yà!! Eríwo Yà!!!

Ṣí Gbogbo Babaláwo àti Oníṣẹ̀ṣe lápapọ̀,

Ní òní yìí (ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, oṣù kejèe 2019) ni ìgbẹ́jọ́ tó bẹ̀rẹ̀ ní ìtàdògún tó kọjá lọ (Tuesday, 9th of July 2019) parí (tí ìdájọ́ sì wáyé pẹ̀lú) lórí ẹ̀sùn oyún síṣẹ́ fún ọ̀dọ́mọbìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ padà sí ìdí Ifá / Ìṣẹ̀ṣe (Tèmídire Àlàbí) ní èyí tó fẹ́ la ikú òjijì lọ látàrí àìbìkítà láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀ (ní èyí tó jẹ́ ìgbà kẹ̀jọ́ fún ọ̀dọ́mọbìnrin mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀) àti ẹ̀sùn ìgbìyànjú láti fi ipá bá ọ̀dọ́mọbìnrin mìíràn sùn nínú ilé rẹ̀ ní ìlú Ìbàdàn tí ẹgbẹ́ Society for the Ifá Practice in Nigeria (SIPIN) fi kan Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì alias Olúwo Jọ̀gbọ̀dọ́ Ọ̀rúnmìlà nílé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Lẹ́yìn tí Olúwo Ifákòleèpin tí ṣe àlàyé lẹ́kùn-rẹ́rẹ́ lórí àwọn ẹ̀sùn tí ẹgbẹ́ SIPIN fi kan Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì ni Omidan Àyìnkẹ́ Ifátòròmádé Adéfẹ́mi tún ṣe àwọn àfikún lọ́tùn lósì sí àwọn ẹ̀sùn náà, tó tún yàn nàná àwọn ẹ̀sùn náà síwájú síi dáradára.

Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì náà ro ẹjọ́ ẹnu rẹ̀, ó sì gbìyànjú láti wí àwọn àwíjàre lọ́lọ́kan-ọ̀jọ̀kan, ṣùgbọ́n lẹ́yìn àwọn àwíjàre wọ̀nyí; tí Ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn gbà pé kò mọ́yán lórí, tí kò sì fi ẹsẹ̀ kankan múlẹ̀, tó tún jẹ́ àṣán irọ́ gburu ní Babaláwo náà ń pa dà sílẹ̀ ni àwọn Babaláwo láti orí aṣojú àwọn ọmọ Awo, Káwolẹ́yìn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ojùgbọ̀nà, Ọ̀tún, Ìyánífá ilẹ̀ Ìbàdàn (Olóyè Fárìnọ́lá Fákẹ́mi), Àgbọngbọ̀n Awo ilẹ̀ Ìbàdàn (Olóyè Ọládẹ̀jọ Onífádé) àti àwọn olóyè ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn tí wọ́n tún wà níbẹ̀, bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ojúlówó ọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí Babaláwo náà ní kíkankíkan láti fi ẹ̀hónú àti àìdunnú wọn hàn sí àwọn ìwà ìbàjé ńláǹlà tí Babaláwo náà hù láti fi ba Ifá jẹ́ àti títa epo sí àlà Ìṣẹ̀ṣe lápapọ̀ àti láti fi ba ilẹ̀ Ìbàdàn lorúkọ jẹ́.

Wọ́n tún sọ ọ̀rọ̀ síwájú sí láti fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ tó sọ sí ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn pé wọn ò tó pe òun sí ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn; wọ́n jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tó sọ náà ju ẹnu rẹ̀ lọ, wọ́n sì bá a wí lọ́pọ̀lọpọ̀. Lẹ́yìn náà ni Babaláwo Ọ̀ṣúnníyì wá bẹ̀rẹ̀ sí ní rawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní kíkankíkan lórí ìkúnlẹ̀ tó wà.

Àràbà Ilẹ̀ Ìbàdàn (Olóyè ńlá Oyèwùsì Àmọ̀ó Fákáyọ̀dé) wá pa á láṣẹ fún un ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn pé kí wọn ó gbé agogo Ọ̀ṣẹ́ Méjì jáde pẹ̀lú ọ̀pá ikú, kí wọn ó máa lù ú lé Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì lórí bí olóyè Akọ́dá ilẹ̀ Ìbàdàn ṣe ń gbé àwọn ìdájọ́ jáde ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

Àràbà ilẹ̀ Ìbàdàn àti Akọ́dá ilẹ̀ Ìbàdàn bínú gidigidi sí olóyè Ifáṣọlá Ifárínú Ọdẹ́yìnmí (Akọ́dá Olúyọ̀lé, Ìbàdàn) tó jẹ́ Ọ̀gá fún Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì ní Ìbàdàn àti Adéyẹfá Adémọ́lá (Káwolẹ́yìn Olúyọ̀lé, Ìbàdàn) látàrí lílọ́wọ́ sí owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ (tí àwọn méjèèjì pẹ̀lú Babaláwo Ọ̀ṣúnníyì mú wá ní ìjẹta 23rd of July) láti fi ra àwọn méjèèjì àti ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn lápapọ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn rẹ̀ tí wọ́n gbé wá sí ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn.

Babaláwo Ọ̀ṣúnníyì mú ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà (5,000.00) àti ọtí ìgò kan lọ fún Àràbà ilẹ̀ Ìbàdàn; bákan náà ló tún fi ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000.00) pẹ̀lú ìgò ọtí kan rán Àràbà ilẹ̀ Ìbàdàn sí Akọ́dá ilẹ̀ Ìbàdàn.

Wọ́n tún tẹ̀ síwájú sí lórí àwọn ẹ̀hónú wọn lórí àwáwí tí Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì ń ṣe wípé, ò ń mú owó àti ọtí náà wá fún Àràbà àti Akọ́dá gẹ́gẹ́bí ẹ̀tọ́ tó tọ́ sí wọn ní ibi ètò Ifá tí ò ń tẹ̀ ni; wọ́n ní ṣe Babaláwo Ọ̀ṣúnníyì ṣẹ̀ ń tẹ Ifá ní ilẹ̀ Ìbàdàn ni? Torí wípé kò dé ọ̀dọ̀ àwọn rí, débi tí yóò mú owó àti ọtí wá sí ọ̀dọ̀ àwọn.

Lẹ́hìn náà ni Akọ́dá ilẹ̀ Ìbàdàn (Olóyè Ifálérè Ọdẹ́gbọlá) wá bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìdájọ́ kalẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ní èyí tó lọ báyìí :

I. Ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn pa á láṣẹ fún àwọn olóyè Akọ́dá Olúyọ̀lé, Ìbàdàn àti Káwolẹ́yìn Olúyọ̀lé, Ìbàdàn pé wọn kò gbọdọ̀ bá Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì ṣe fún odidi oṣù mẹ́ta gbáko lọ́nà kan tàbí òmíràn.

II. Ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn pa á láṣẹ fún Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì pé kó dọ̀bálẹ̀ fún Olúwo Ifákòleèpin láti fi tọrọ àforíjìn lórí ìwà àrífín àti ìjọra-ẹni-lójú tó hù sí Àgbà Awo náà. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lójú ẹsẹ̀.

III. Ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn tún pa à láṣẹ bákan náà pé kí Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì ó tún dọ̀bálẹ̀ fún Omidan Àyìnkẹ́ Ifátòròmádé Adéfẹ́mi láti bẹ̀bẹ̀ fún ìwà àìmore tó hù sí lórí ipa ribiribi tí arábìnrin náà kó lórí ọ̀rọ̀ náà, pàápàá lásìkò tí Irenìtemi Àlàbí wà ní ilé ìwòsàn fún iṣẹ́ abẹ láti ra èmi rẹ̀ padà.

IV. Ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn tún pa á láṣẹ fún Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì kí ó dà owó tí iye rẹ̀ ń lọ bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba náírà (about two hundred thousand naira) tí àwọn Babaláwo dájọ láti fi ṣe iṣẹ́ abẹ pàjáwìrì fún Tèmídire Àlàbí láti fi gba ẹ̀mí rẹ̀ kalẹ̀.

(ṣùgbọ́n Olúwo Ifákòleèpin àti omidan Àyìnkẹ́ Ifátòròmádé Adéfẹ́mi ní àwọn tí yọ̀ǹda gbogbo owó náà fún Ifá, pé kí ó má wulẹ̀ dá owó náà padà mọ́)

V. Ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn pa á láṣẹ fún Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì pé kí ó dẹ́kun láti máa fi Ifá pa irọ́ láti máa fi bá àwọn ọmọbìnrin sùn tàbí fi Ifá dá ẹ̀rù ba àwọn obìnrin lórísirísi tó ti fẹ́ rí, tàbí tó tún ń fẹ́ lọ́wọ́ kí ilé ayé rẹ̀ ó máa ba ṣe bàjẹ́ pátápátá.

VI. Ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn tún pa á láṣẹ fún Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì pé kí ó lọ jáwọ́ pátápátá nínú ìwà èérí tí ó jẹ mọ́ pé ó n fi ipá bá àwọn obìnrin sùn (pàápàá àwọn tó ń wá ṣe Ifá lọ́dọ̀ rẹ̀ tàbí àwọn ọmọ Oníṣẹ̀ṣe lápapọ̀).

VII. Ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn tún pa á láṣẹ fún Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì pé kò gbọdọ̀ pe ara rẹ̀ fún ẹnikẹ́ni mọ́ pé òun ni Olúwo Ifá ìlú Ọ̀yán ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Odò Ọ̀tìn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun nítorí wípé ìwádìí ìjìnlẹ̀ fi ẹnu rẹ̀ múlẹ̀ pé kòsí Olúwo ní ìlú Ọ̀yán lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, wọn kò tíì jẹ Olúwo mìíràn láti ìgbà tí Olúwo àná ti ṣẹ́ Òṣùn. Wọ́n tún fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé kò le fi ara rẹ̀ jẹ Olúwo bó ti wù kí ó wù ú tó, torí wípé ọmọ ilé Ọlá Fáṣìpẹ̀ ni, kìí ṣe ọmọ agbo ilé tí wọ́n tí ń jẹ Olúwo (tó jẹ́ oyè agbolé wọn), wọn kìí sí jẹ oyè Olúwo ìlú Ọ̀yán nílé wọn, ègún ni!

VIII. Ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn wá pa à láṣẹ fún Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì pé ó gbọ́dọ̀ fẹ́ (gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀) ọ̀dọ́mọbìnrin tó ṣẹ́ oyún fún náà (Tèmídire Àlàbí) nígbà tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ́ níwájú Ọ̀ṣẹ́ Méjì wípé ìyàwó kan ló sì wà lọ́wọ́ òun bayìí, ọmọ kan ṣoṣo ni ò ń ṣẹ̀ṣẹ̀ bí àti pé Ifá nìkan ló le sọ iye ìyàwó tí ò n máa fẹ láyé òun.

Babaláwo Ọ̀ṣúnníyì tún fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́ síwájú sí pé, ò ń ti lọ rí àwọn ẹbí ọmọbìnrin náà (Tèmídire Àlàbí) ní Máfolúkù Oshodi, Lagos, tí gbogbo wọ́n sì ti fi ọwọ́ sí fífẹ́ ara àwọn méjèèjì.

Lẹ́yìn ìdájọ́ yìí ni ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn lábẹ́ àṣẹ Àràbà ilẹ̀ Ìbàdàn pá á láṣẹ fún Babaláwo Ọlájídé Ọ̀ṣúnníyì pé “ó gbọ́dọ̀ san” lórí ọ̀rọ̀ yí, torí wípé ó jẹ̀ ẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn gbogbo tí wọ́n fi kàn án.

Ilé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn jẹ́ kó di mímọ̀ fún Babaláwo Ọ̀ṣúnníyì pé, yíò jẹ́ ìṣòro fún ọ̀dọ́mọbìnrin náà (Tèmídire Àlàbí) láti le fẹ́ ẹlòmíràn (pàápàá nídìí Ifá tàbí inú Ìṣẹ̀ṣe lápapọ̀) nítorí wípé ó ti “pa àlè le” lórí.

Àbọrú!
Àbọyè!!
À bọ ṣíṣẹ o!!!

Adérèmí Ifáòleèpin Adérèmí
Founder and Chief Coordinating Officer
Society for the Ifá Practice in Nigeria (SIPIN)

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

orisa

The World of the Yoruba Orisa