Home / Art / Àṣà Oòduà / Eto Olobe Loloko: Sokoyokoto !
olobe

Eto Olobe Loloko: Sokoyokoto !

Adupe lowo eledua, oba alaanu, olorun to ohunkohun ko sooro se fun lati se,Adupe lowo olorun ti o tun ka wa ye ni ojo toni, a ki gbogbo wa ku bi oju ojo ti ri oo, nigiriya a kuku de’run fun gbogbo wa lase edumare (amin) Gege bii okan lara awon ateranse ti a ri gba ni ose ti o koja, wipe ki a mu lara ounje ijebu wa si ori eto, tooo a ti se bii e ti wi oo. Loni IKOKORE IJEBU, ni a mu wa, e ma ba mi kalo..

Awon ohun elo ti a o lo fun IKOKORE wa ti oni ree;-

ISU
ATA GIGUN
EPO
ALUBOSA
EDE
EJA
PONMO
EJA PANLA
IYO,

Bi a o ti poo po ti yoo di odindi ree.
IGBESE AKOKO: A o koko be isu wa, a o ge si kekere, a o si rin. (a le fi iyo die si inu isu yen leyin ti a ba rin-in tan, ki a fi poo papo, ti o ba wu wa ni o)

IGBESE KEJI:– Leyin eyi, a o gbe omi die ka ina, a o da ata sii, ti ata yii ba ti n hoo, a o da ede, eja panla gbigbe, eja, ponmo, Maggi ati iyo die a o de pa ki o hoo fun iseju marun.

IGBESE KETA:-leyin eyi, a o wa ma rora da isu wa ti a rin yen si inu ata obe yen, (bi a se da okara tabi egusi sinu epo), a o wa fi epo die sii, e o si de pa, ki o hoo fun iseju mewa tabi jubeelo.

(AKIYESI) :-Leyin ti obe yi ba ti n ho ni ori ina, a le fi sibi obe wa fo Koko isu yen, ti koko yen ba tobi ju ) .Ti o ba ti jina, ti a too wo, ti o si dun, IKOKORE ijebu ti de’le niyen.

Ki a ma jeun lo ni o ku bayi, A le jee pelu eba tutu, aje boko doweke, aje digboluoko,’yemi ara ijebu, ewe sooooo

Too a o ni ri ju bayi lo lori eto olobe loloko sokoyokoto toni, emi omo yin, aburo yin naa ni OMIDAN FALADE OPEYEMI WURAOLA. Aye wa fun Amoran, Afikun, Ayokuro ati ibeere.
Nje a ri eni ti o ni ibeere bii.?

~Falade Opeyemi Cecilia

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti