Home / Art / Àṣà Oòduà / Eto Olobe Loloko Sokoyokoto Toni
olobe

Eto Olobe Loloko Sokoyokoto Toni

Olorun ogo ni fun oruko re, oba to ni kokoro Iku ati iye lowo, oba ti o le pa, oba ti o le ji, adupe lowo eledua, oba ti o fi aanu re pawa mo.
“FURAIDI IRESI” (fried rice) ni ounje aladun ti a o fi ko ara wa leko loni,,,,
Awon ohun ELO ti a o lo lati se IRESI FURAIDI owun ree…
RICE
ORORO
ALUBOSA
IYO
MAGI
ALUBOSA ELEWE
CARROTTI
EDO ERAN
CURRY
THYME
EWA ALAWO EWE(green peas) IGBADO DIDUN(sweet corn)
Bii a o ti se iresi furaidi wa re oo, e ma bami Kalo :-ONA meji ni a le gba se iresi wa:-ONA KINNI RE O:-
IPELE AKOKO;- A o Koko san, carrotti, alubosa elewe, edo wa ti a ti bo yen ati alubosa, a o wa ge si kekeke. A o san iresi wa daradara,
IPELE IKEJI;- Leyin ti a ti pari ipele akoko,a o gbe iresi wa ka ina, a o se fun igba die(parboiled), a o so kale, a o si daa sinu ase kan.
IPELE IKETA;-Leyin eyi, a o da ororo si ori ina, ti ororo yii ba ti gbona, a o fi alubosa die si, a o carrotti si, alubosa elewe, curry, thyme, omi eran,alubosa elewe, Maggi die ati iyo die si, a o ro papo, ti a ba rii wipe omi eran yen kere, a le fi omi die si.
IPELE IKERIN;- leyin eyi, a o wa da iresi wa si, a o ro papo, a o ni je ki omi poju ninu iresi yen, a o wa de pa, a o sii yewo leyin iseju mewa,, leyin eyi, a o da edo sii.
IPELE IKARUN;- Leyin iseju mewa, ti a ba rii wipe iresi wa ti jina daradara, a o san ewe alawo ewe wa(green peas,) ati igba didun wa(sweet corn) .
IPELE IKEFA;-iresi wa ti dele niyen, a le je pelu, moinmoin, dodo, ati bee bee lo.
,,,,,,,,,, ONA KEJI TI A LE GBA SE IRESI FURAIDI,,,,,,,,,,,,,
IPELE KINNI:-a o San iresi wa daradara, a o da sinu ase kan, ki o le ma rooo IPELE KEJI:-, a o gbe oro ka ina, a o fi curry ati thyme die si, leyin eyi, a o wa da iresi wa sini ororo yen, a o si maa ro papo, ninu ororo yen, titi ti oju iresi yen yio fi yipada die, IPELE KETA:-leyin eyi, a o da carrotti, edo, aluboda elewe sii inu iresi yen, a o roo papo, a o wa omi eran wa si tabi Maggi ati iyo die, ao si de pa ki o le jina, IPELE KERIN :-leyin ti o ba ti jina tan, a o fi ewa alawo ewe ati igbadun sii, iresi wa ti dele niyen.
Too a o ni ri ja bayi lo lori eto olobe loloko sokoyokoto toni,, oruko temi ni OMIDAN FALADE OPEYEMI WURAOLA.
Aye wa fun Amoran, Afikun, Ayokuro tabi ibeere! Nje a ri eni ti o ni ibeere bii??

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Ọdún orò gbìnà yá, ìdájí ní àwọn olórò yóò fi máa yíde ìlú níṣẹ̀yin

Fẹ́mi Akínṣọlá Ṣe aifẹsọ kebosi,lai rẹni jo o,ati pe n ta o ba fẹ o bajẹ,o ni bi o ṣe yẹ ka ṣe e,eyi lo bi atunse abẹnu lati fopin sawuye wuye to waye latari aawọ to suyọ laarin awọn onisese ati awọn ẹlẹsin meji ti o ku(Kitẹẹni ati Musulumi).Wayi o, igbakeji alaga fun ẹgbẹ agbaagba nilu Isẹyin, Alhaji Bọlaji Kareem, ti kede pe ija ti dopin, ogun si ti tan lori aawọ ọrọ sise nilu Isẹyin.Kareem, ẹni to soju ...