Kàyééfi ńlá gbáà ni súnkere fàkere okò tí ó selè ní ìròlé àná ní bóòsì dúró Agric (Agric bus stop), Ikorodu ní ìlú Èkó. Tí ó kan ògá pátápátá ilé-isé olóòpá (commissioner of police) Ògbéni Fatai Owoseni láti yo òpòlopò ènìyàn nínú súnkere fàkere tí ó selè ní bóòsì dúró Agric.
Gégé bí ìròyìn se so àwon ò n tajá àti ò n rajà ti férè gba ìlàjì ojú ònà tán, tí won sì fi ònà díè sílè fún àwon tí ó ni ònà, èyí fa ìdádúró púpò fún òpòlopò ènìyàn tí àwon míràn sì dúró sinsin.
Nígbà tí Ògá olóòpá (CP) ń bò láti Ikorodu ó sò kalè láti rìn lo sí bóòsì dúró (bus stop) láti mo ohun tí ó fà á.
Nígbà tí LASTMA tí kò leè gba ara rè sílè, àti àwon tí ó ń darí maalo maabò àti ìgbìmò egbé awakò (NURTW) dúró láìrí nkankan se, ògá olóòpá àti àwon emèwà rè lé àwon tí ó ń tajà ní ojú ònà yí kúrò tí gbogbo rè sì lo sí rowó rosè kí ó tó kúrò lo sí Ikeja.
Kò saláì fi ìkìlò sílè kí ó tó lo wípé ohun kò fé rí àwon olójà kankan ní ojú ònà mó láéláé…..
English Version
Contnue after the page break
Pages: 1 2
Tagged with: Àṣà Yorùbá