Home / Art / Àṣà Oòduà / Idile Alayo Toni
yoruba

Idile Alayo Toni

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Idile Alayo wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Idile Alayo ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.
Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-
“Olootu mo ki yin e ku ise o, ko ni reyin lase Edumare. Mo si ki gbogbo awa ololufe eto yi pupo wipe, ibanuje ko ni wo ile alayo enikookan wa o.  Ase.
Olootu e jowo oro kan ni nsele ninu ile mi, ti mo fe ki awon oloye eniyan ba mi da si. Lati igba ti mo ti wa ni kekere ni mo ti korira ki oko ati iyawo maa ja, koda maami a ma so fun mi wipe ti awon ati baami ba ni gbolohun aso ninu ile lasan nse ni ara mi ma n gbon ti otutu yoo si bere si maa mu mi. Ni akoko ti mo wa dagba tan ni mo wa korira iwa yi julo, koda ti mo ba ri oko ti n na iyawo re, nse ni n o maa wo iru okunrin be bii were ti opolo re ti daru, ti ko si mo ohun ti o nse.
Ni bayi emi pelu ti di oniyawo nile, Isele ti o wa nsele simi bayi wa fe mu mi si iwa hu, EMETA otooto ni iyawo mi ti fun mi ni igbati, afi bi eni wipe arabinrin yi ti se ise ologun ri ni, awon igbati wonyi kii se igbati ti o rorun rara, igbati ti ma n fa otutu fun eniyan ni. mo si ti ba Eleda mi se ipinnu wipe nko le gbe owo mi soke na iyawo mi laye. Beeni mo korira ikosile pupo.
Oro yi wa fe toju sumi, tori ni akoko ti isele yi sele, mo pe awon obi arabinrin yi mo si fi ejo omo won sun won, looto won pe iyawo mi ni akoko yi ti won si baa so eyi ti nje okodoro oro sugbon leyin re ni arabinrin yi la mi ni ifoti elekeji, leyin elekeji yi ni mo pe awon ebi mi ati ebi iyawo mi pelu ti gbogbo won si panu po da soro yi ti iyawo mi si n wa omije loju ni ojo yen loun wipe iru re ki yoo waye mo. Afi bi arabinrin yi se la mi ni ifoti eleketa ni ose ti o koja yi.
Mo ti wa rii bayi wipe arabinrin yi ko le dawo iwa yi duro laisi atunse, ni ojo isinmi ti o koja lo yi ni emi ati awon ore mi meta kan jo wa nile oti, beeni oro yi wa n gbe mi lokan, ni mo fi ogbon gbe oro yi kale lati gbo amoran lenu awon ore mi, ni mo tenu bo oro wipe aburo mi kan ni o ma fi ejo iyawo re sun mi o, nse ni o wipe emeta otooto ni iyawo oun ti la oun ni ifoti, beeni oun si ti fi ejo re sun awon obi re lopo igba sugbon ko si ayipada. Oun si ti ba Eleda oun pinnu wipe oun o le gbe owo soke na obinrin laye, beeni oun o fe ko iyawo oun sile leyin omo meji, iyen ni mo ni ki n gba amoran lenu yin. Okan lara awon ore mi ti oruko re nje Kola ni o ko soro, e gbo bi Kola ti wi.

“Ore iyawo aburo re gba aburo re leti ni emeta otooto, ko si ri nkan se sii, se won nse ere ori itage ni abi tooto ni oro na? se sulu ganbari ni oruko aburo re ni? Haaaa awusubilahii, emi laye mi, abi won o san owo omogo lojo ikomo aburo re ni? Iwo gan o si wa mo iru esi ti o le fun-un, woo ore esu ni won fi n wo esu, ma si foko mi se ona ojo kan ni a nko o, toba se akoko ti iyawo re dan an wo ni o ti daa pada fun Un ni, walahi ko ni dan iru re wo mo, obinrin yoo gba emi leti, kamari ni Poolu wi…… ”

Jimo ekeji lara awon ore mi ko je ki Kola dele ti o fi gba oro moo lenu, ni iyen wipe ” Kola kilode ti Iwo ki n fara bale bayi, waduwadu sa ni gbogbo nkan tire, se okun a maa wo ruru ki a waa ruru ni? Sebi won ni ti oko ba je agutan kii iyawo je ewure ni, ti iyawo ba si je agutan oko re pelu yoo je ewure, eko gbigbona nfe suuru jare. Ti o ba si wa da ifoti luu ti iyen si subu lule rogbondan nko se o mo wipe o di apaniyan niyen? Ni Jimo koju si mi ti o si mi kanle ti o bi mi leere oro “Hmmmm ore nje o tie bi aburo re, iru iwa ti o hu ti o fi di ogun onigbati? Ni mo daun wipe, o ni ti awon ba ni ariyanjiyan lasan ninu ile ni o. Ni Jimo tun bi mi wipe se aburo re si maa n se ojuse re ninu ile gege bi oko? Ni mo daun wipe, looto nko ba won gbe sugbon o ngbiyanju. Ni Jimo daun wipe nibi ti oro de yi toba je ododo ni gbogbo idaun re wonyi, so fun aburo re wipe ni ojo ti iyawo re ba tun daa lase, nse ni ki o gbe sinu oko ki o si gbee lo odo awon obi re, ki o yonda omo won fun won laaye, so fun Un wipe ko gbudo naa o….”

Jimo koi ti danu duro ti Kola fi da oro moo lenu, ni o wipe, “abi e o maa gboro se amoran gidi ree, ki o ko iyawo re? Ti o ba wa ko onigbati ta ni o mo boya elese tabi onigigigbo ni yoo tun fe? A ni ki o koo leko ti ko duro ko nile won, Olorun o ni je ki n rina ninu konga, emi laye mi haaaaaa” nigba ti mo rii wipe fanfa oro yi ti fe maa di nkan miran laarin awon mejeeji ni mo da won lekun, ti mo si wa koju si Tunde iketa won wipe, ore se oti ni ko je ki o da soro ile yi ni? Ni Tunde daun wipe:-

“Oro wo ni o fe ki n da si, se oro rurun ti e nso yi abi omiran? Iyawo aburo re gbaa leti ni emeta otooto ko si ri nkan se sii, duro na se e ro wipe gbogbo okunrin ti won n na iyawo won ni kii se okunrin gidi ni, abi e ro wipe gbogbo awon okunrin ti o ko iyawo won sile ni ika eniyan? Sebi eniyan eleran ara ni gbogbo wa, ti obinrin ba fitina eniyan nigba miran, nse ni yoo dabi ki o yo ibon ti won, emi ti o nwo yi, mo korira ki okunrin maa na obinrin ju igbe lo sugbon lojo ti yoo sele, koda iyawo mi ti je igbaju ati igbamu bii mefa ki nto mo wipe iyawo mi ni mo n na, woo emi o ni ki aburo re na iyawo re o, sugbon amoran temi ree, niwon igba ti aburo re ti fi ejo iyawo re sun fun awon ebi mejeeji ti kosi si ayipada, aburo re ko si fe na iyawo re beeni ko fe ko iyawo re sile, ennnn so fun Un wipe, TI IYAWO RE BA GBA A NI ETI OTUN, KI O YI TI OSI SI, BI O SI GBA A NI TI OSI KI O YI TI OTUN SI, KI WON MAA BI SII, KI WON MAA RE SII, KI O SI MAA GBA YINNNN NINU IFOTI, ko ju baun lo”

Bi Tunde ti danu duro ni gbogbo won bu si erin, ti a si dide lori ijoko, bi mo ti dele ni ojo ti a nwi yi ni mo n da oro na ro, mo nro oro awon ore mi lokookan ewo wa ni oluware yoo se bayi, oro Tunde ni o tie je kayefi fun mi, KI N MAA BI SII, KI N MAA RE SII, KI N SI MAA GBA YINNNN NINU IFOTI. iyen ni mo se ni ki n fi oro na to yin leti ki awon ojogbon eniyan la mi loye, iru igbese wo ni a ngbe siru oro bayi, ewo ninu amoran awon ore mi wonyi ni o see tele, bi ko si si eyi ti o dara, e jowo ki ni ki nse bayi? ”
Oro ree o eyin oloye eniyan, paapa julo eyin baami ati maami nile, eyin ojogbon eto idile alayo, e jowo ti eniyan ba wa niru ipo bayi, ki ni sise gan, se were ni a fi nwo were ni abi ki a kuku see ni orisa bi o le gbe mi, se mi bi o ti ba mi? Abi ki oluware kuku maa muu mora ki a gba wipe iya ife ni? Eyin ojogbon oro ree oooo

About ayangalu

5 comments

  1. Segun Akerele

    hun oro buruku toun terin

  2. Kenny Fasemore

    Moki olootu ati atokun eeto yii, olumoye ti ilumoye akoko, koni suyin, koni reyin o, moki awon ojogbon ti yio maa dasi oro yii wipe, opolo wa koni daru oo.
    Oro buruku, t’ohun t’erin, ilu gangan ni oro ile yii, ti o ba koju si enikan, a si ko eyin si elomiran, bi oro se ri lodo arakunrin yii, o le maa ribe lodo elomiran.
    Bi oro ti wa ri yii pelu gbogbo alaaye arakunrin yii, amoran temi ni wipe, ki arakunrin yii pa obinrin yii ti patapata si egbe kan, ko pati pelu iwa eranko ti o n wu yen, nigbati arabinrin yii naa ba ri wipe oun o ri oju oko oun mon rara, yio pe aaro ati odofin inu re yio bawon soro.

    Sugbon, moni gbolohun kan fun iyawo yii naa o, kosi asegbe mon laaye oo, asepamo lo wa o, sebi oun naa bi omo okunrin, bi iyawo omo re yio se maa laa omo t’oun naa ni ifoti niyen, leyii ti yio tun lagbara ju, eyi ti oun nse fun oko re lo.

    • Gbolahan Sotomi

      Hmmm alagba Kenny Fasemore mo ki yin o, ile ati ona tiyin na ko ni daru lase Edumare. E jowo bawo ni eniyan yoo ti pa iyawo re ti gan, ti won yoo maa jo sun lori ibusun kan na, won yoo ma jeun ninu ikoko obe kan na, kosi si bi won o jo ni ma soro po ninu ile niwon igba ti won jo ngbe po. Abi bawo ni o se rorun? E jowo e La wa loye o.

  3. Kenny Fasemore

    E seun kabiyesi, ti won ba tun n se gbogbo awon nkan ti e ka sile yii, o tumo si wipe, oro ile yii ko je edun okan fun arakunrin yii niyen.

    Ti won ba jo sun ori ibusun, yio ko eyin si nii, tabi ti o ba see se, ki o maa kuku sun papo pelu re lori ibusun kanna, yio ko ounje re sile fun, ki o maa lo fun ni ogun ekute je, kosi nkan to n je awaada tabi apaara, nipa idi eyi, obinrin naa yio mon wipe, ese nla ni oun da, mosi mon wipe kosi eni ti obinrin naa yio ro ejo fun ti won yio daa la’are

  4. Kabiesi Mokiyin O ,eku Ko Le Da ,ile Ati Ona Tiyin Na Ko Ni Daru,alagba Yakubu Bukky Padi Mi Dada Eku Eto , Amoran Ti Emi Ma Fun Arakunrin Yi Ni Wipe To Ba Mo Wipe Oun Sini Fe Obinrin Yi ,ko Pinrintendi Ko Se Bi Wipe Oun Tin Fe Iyawo Miran Sita ,ojo To Bati Beere Wala Ko Bo Sita Ko Mu Aso E Bi Meta Ko Jade Bi Ojo Meta Ko Ma Wa Le Ojo Kerin Ko Wa Le ,to Ba De Le Ko Ba Awon Omo E Sere Kowa Se Bi Wipe Ago Oun Dun Ko Gbe Seti Ko Ni Elo Dear Moti Fe Ma Bo ,kilo Se Sile Henhen Amala Dudu Ok Mi Ni Pe Ma Kan Lara Mo Nbo ,eeri Wipe Kia Obirin Yen Adogbon Ma Jentu Diedie A Ma Ro Pe Aboto Abiro Ni ,ewo Olotu To Ba Se Be Fun Larin Osu Kan Ewo A gba Foga E Ni Lori Ere Ayafi To Ba Je Pe Oun Lounbo Oko Yen O

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti