Home / Art / Àṣà Oòduà / Idile Alayo Toni 09.06.2016
idile alayo

Idile Alayo Toni 09.06.2016

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Idile Alayo wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Idile Alayo ti ose yi. Beeni mo ki gbogbo awa musulumi ododo wipe a ku ongbe o, emi wa ti o bere re ni yoo pari re lase Edumare.

E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.

Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-

“Olootu mo ki yin pupo fun ise takuntakun ti e n se lori eto yi, Eledua yoo tun ile ati ona tiyin na se o, mo si ki gbogbo awa ololufe eto Idile Alayo wipe ile alayo gbogbo wa ko ni di ibanuje lase Edumare. Ase

Olootu oro kan ni o n dun mi lokan ti mo nilo amoran awon ojogbon, odun iketa ree ti mo ti wa nile oko, ti Eledua si ti fi omo kan da mi lola, ise awon ti nko ile ni oko mi nse ti Eledua si gba fun un lenu ise owun. Ko si ipinle na ni orile ede wa nibi ti oko mi kii tii lo se ise, nse ni won ma n pee lotun losi tofi je wipe oko mi le lo ni osu kan si meji nigba miran laiwa si ile.

Looto kii se wipe bi ise se maa n gbe arakunrin yi kiri yi ko dun mo mi ninu nitori mo mo wipe atije atimu ni o nba ka beeni mo si ti mo arakunrin yi pelu ise re ki n to fe e, sugbon ohun kan ti o n sele ti o si n kan mi lominu ni wipe o fere je akoko ti oko mi ko ba si nile pelu mi ni inu mi ma n dun wipe mo ni oko, o fere je akoko yi nikan ni mo ma n ri ayo ile oko, o fere je akoko yi nikan ni mo le fi oko mi yanga sugbon ni kete ti oko mi ba pada de nse ni ebi wa ma n di ebi alariwo.

Oro yi si wa n je edun okan fun mi, tori ti oko mi ba wa ni irin ajo nse ni yoo maa ba mi soro lori ero ibanisoro bi eni wipe laisi emi ko si oun pelu, nse ni awa mejeeji yoo ma da oweke lori ago, opolopo oro apani lerin, opolopo amoran, ati oro tutu lolokan ojokan ni oko mi yoo maa so simi toje ti mo ba soro pelu oko mi tan inu mi a si maa dun, maa si ma dupe lowo ori mi ti o gbe mi pade arakunrin yi sugbon ni kete ti oko mi ba pada sile ni oro yoo wa yi pada. Emi ati oko mi yoo wa maa sebi ologbo ati ekute ninu ile.

Oro yi a si maa gba omije loju mi lopo igba tori nse ni mo n ro wipe se nkan miran wa nidi oro yi ni? Koda mo ti gbawe gbadura lori oro yi sugbon ko si ayipada, opolopo igba ni mo ti ji oko mi ni oganjo oru ti mo si bii leere wipe ki ni ma nfa sababi ede aiyede wa gan ti yoo si daun wipe emi ni mo ma n faa, nje ona wo ni mo fi ma nfa gan? Ni yoo ba wipe ki n lo ye ara mi wo.

Oro yi le ma ni itunmo si elomiran sugbon ohun ti n gba omije loju mi gan ni, abi ewo ni ki eniyan ri oko re ti o ye ki o je idunnu re ti yoo si wa je ibanuje fun oluware, ti a ba si n soro lori ago nse ni yoo dabi eni wipe awa ni loko laya ti o dara Julo ni agbaye. Beeni awon oro ti ko to nkan ni o si ma n saba da gbonmi si omi o to yi si. Oro yi ti wa toju sumi pata pata bayi, iyen ni mo se ni ki n fi lo eyin iya ati baba mi ti e mo nipa oro loko laya tori won ni iriri sagba ogbon.

E jowo ki ni ma n se okunfa iru isele yi gan ati pelu ki ni ona abayo, e dakun eyin oloye eniyan, e la mi loye o”

Hmmm oro ree o eyin ojogbon ati oloye eto idile alayo, aja ti o ri olowo re lokere, ti o si kun fayo, ti o nfo soke sile ti olowo re wa sun moo tan ti ngbo fita fita, se aja ni ki a da lebi ni abi olowo re ni ki o ye ara re wo? Eyin ojogbon o dowo yin o

`Abel Simeon Oluwafemi

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti