Home / Art / Àṣà Oòduà / Idile Alayo Toni – 17.09.2016 (E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo)
african traditional religion symbol

Idile Alayo Toni – 17.09.2016 (E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo)

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wi pe a ku aseku odun emi wa yoo se pupo re laye, layo ati ni alafia ara. Mo si ki awa ololufe eto yi, wi pe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.
Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-
“Olootu mo ki yin pupo a ku aseku odun, a o jo se opo re laye lase Olodumare. E jowo olootu oro kan ni nsele laarin emi ati iyawo mi ti mo nilo amoran awon ojogbon lori re.
Musulumi ni baba ati iya ti o bi mi lomo, esin isilamu ni emi pelu si yan laayo, idile Musulumi ni iyawo mi pelu ti wa ti oun pelu si je omo leyin Anobi.
Ki n to di oniyawo nile n o kii fi odun ileya sere rara, ko si bi nkan yoo ti ri, n o de Odo awon obi mi lati lo ba won se odun. Beeni lati bi odun marun seyin ti mo ti se igbeyawo, ile baami ni emi ati ebi mi ti maa n se odun ileya.
Sugbon ni odun ti o koja lohun ni iyawo mi sa dede pe mi leyin ti a de nile odun ti o si bi mi wipe:- Baba Muri, e dakun e ma binu si oro ti mo fe so yi o, e jowo kilode ti o fi je wi pe odo awon dadi labule ni a ti maa n lo se odun ni gbogbo igba? Mo ro wi pe nigba ti Olorun ti gbo adura wa, ti awa pelu ti di onile lori, ti awon omo si ti wa nile, nse ni o ye ki awa pelu maa se odun nibi ti Eledua jogun fun wa ke! Emi o ro wi pe ohun ti o bojumu ni ki a maa ti Ile wa pa lodoodun ki a si kori sabule, iyen ni mo ni ki nba yin so o”
Hmmmm bi iyawo mi ti danu duro ni mo bii wi pe, se e ti dele? O si daun wipe, “beeni oro mi o ju baun lo” ni mo dupe lowo re pelu ohun suuru ti o fi gbe oro na kale, mo si wa se alaye fun un wi pe bi mo ti maa n se ki n to di oniyawo ni eyi ati wi pe kii se emi nikan, gbogbo ebi wa ni a maa n pade ni ile odun yi lati mu awon baba ati mama lara ya, ko wa ni bojumu ki o je emi ni yoo da akojopo yi ru tori emi gan ni mo mu ero yi wa fun awon ti o ku. Sugbon tobe jube lo n o gbe oro na ye wo ti o ba ni ogbon ti a le da sii n o je ki o gbo ti o ba to akoko.

 
Beeni iyawo mi daun wi pe “Ki e ya wa ogbon da si ni o” beeni a mu enu kuro lori oro yi, sugbon bi odun ti a se koja yi ti n sunmo’le ti iyawo mi si se akiesi wi pe, mo ti n se imura abule, ni o bi mi wi pe “Baba Muri se odo awon dadi labule ni a tun n lo lodun eyi ni”?
Mo si daun wi pe “Beeni” ni o daun wi pe “O da ko buru o” bi a ti wa pada de labule ni ano ode yi, ni iyawo mi pe mi ti o si wi pe “Baba Muri se e mo wi pe mo ti gbiyanju to? Sebi e mo wi pe olodun ni awon obi emi gan pelu, ki Eledua so wa ju amodun lo, ti o ba ti di odun ti nbo, ti a ko lee se odun ninu ile wa nibi, ti e ba ti kori si odo awon obi yin beeni emi pelu yoo lo ba awon obi mi sodun, oro mi ko ju baun lo o”

 
Hmmmm ni mo mi kanle ti mo si wi pe “obinriiiinn” nko dun gbolohun kan ju eyi lo, lati akoko na mo wa n gbe oro yi ye wo sotun sosi koda ko ye mi, abi oluware yoo si wa pa awon obi re ti nitori iyawo re bi? Beeni bi a o si se ohun obinrin fe, oluware o le gbadun ile re.
E jowo ki ni o buru ninu ki emi ati ebi mi maa lo se odun pelu awon obi mi? Eyin baami ati maami nile, e jowo mo nilo amoran yin, bawo ni n o se yanju oro ile yi, ogbon wo ni mo le da sii tori nko fe ki oro yi da gbonmi si omi o to sile laarin emi ati iyawo mi, iyen ni mo se ni ki n fi oro na lo yin ki e ba mi fi ojo agba woo, oro mi ko ju baun lo o”
Oro ree o eyin ojogbon ati oloye eniyan e jowo e ba wa fi oju sunukun wo oro ile yi, abi a o kuku le da arabinrin yi lebi tori ati eni ti won bu iya re ati eni ti o bu iya oniya awon mejeeji ni won yoo kuku ri ejo ro, bee kede re, se a o wa ni ki oko iyawo pa ojuse re ki o to pade iyawo re ti ni? Eyin oloye eniyan se won kuku wi pe enu agba lobi ngbo si, o dowo yin o….

 

Abel Simeon Oluwafemi

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

masoyinbo

#Masoyinbo Episode Seventy-three: Exciting Game Show Teaching Yoruba language and Culture