Home / Art / Àṣà Oòduà / Ìdíle Saraki àti ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dájọ́ ìpàdé
saraki

Ìdíle Saraki àti ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dájọ́ ìpàdé

Ìdíle Saraki àti ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dájọ́ ìpàdé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Lẹ́yìn tí Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara ti tẹ̀lé òfin tí wọ́n wo ohun ìní ìdílé Saraki èyí tí wọ́n ń pé ibẹ̀ ni Ilé Arúgbó ní ìlú Ilorin, ìpínlẹ̀ Kwara, gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kan nínú rẹ̀ ti wá gbà láti yanjú aáwọ̀ láì ti ọwọ́ Ilé ẹjọ́ bọ̀ ọ́ mọ́.

Lásìkò ìgbẹ́jọ́ náà ní ilé ẹjọ́ gíga ti ìpínlẹ̀ Kwara lọ́jọ́ ẹti ọ̀sẹ̀ tó kọjá, àwọn Agbẹjọ́rò fún àwọn ọlọ́rọ̀ méjéèjì sọ fún adájọ́ Abiodun Adewara pé àwọn ti jọ gbà láti yanjú ọ̀rọ̀ láì wá sí Ilé ẹjọ́.

Bákan náà ni wọ́n fi ìpàdé sí ọjọ́ kẹtadínlọ́gbọ̀n oṣù kínní ọdún yìí lórí ọ̀nà àti wá ojútùú sí ohun tó wà nílẹ̀.

Èyí ló mú kí Adájọ́ Adewara gbóríyìn fún igun méjéèjì tó sì kí wọn fún akitiyan wọn láti pinnu pé àwọn fẹ́ yanjú aáwọ̀ láì wo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Nítorí náà, adájọ́ sún ìjókòó síwájú di ọjọ́ kejì oṣù kẹta ọdún 2020 láti gbọ́ àbọ̀ ìyànjú aáwọ̀ náà.

Bí ẹ kò bá gbàgbé, ọjọ́ kejì oṣù kínní ọdún yìí ni ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara fi àwọn ọkọ̀ katakata wó ilé Arúgbó èyí tí wọ́n ní olóògbé Oluṣola Saraki tó jẹ́ bàbá Sẹ́nétọ̀ Bukola Saraki kọ s’órí ilẹ̀ tí wọ́n ní ó yẹ kí Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara lásìkò rẹ̀ fi kọ iléeṣẹ́ ìjọba.
Lórí èyí, ìdílé Saraki gbé Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara lábẹ́ àkóso gomina AbdulRahman AbdulRazaq lọ sílé ẹjọ́ lẹ́yìn tí wọ́n wó ilé náà palẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, adájọ́ Adewara gbà wọ́n níyànjú láti gba àlàáfíà láyè kí wọ́n sì jíròrò láti pẹ̀tù sí aáwọ̀ tó ń ṣúyọ lórí Ilé tí wọ́n wó.

Èyí sì ló mú kí ìdílé Saraki pè fún ìpàdé láti yanjú rẹ̀ pẹ̀lú Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara láì ti ọwọ́ òfin bọ ọ̀rọ̀ náà mọ́.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Saraki

Saraki Tackles Buhari, Says Eighth Senate Organised Security Summit

Former President of the Senate, Dr. Bukola Saraki, yesterday faulted the claim by President Muhammadu Buhari that the Eighth Senate did not assist his administration to battle insecurity by organising a summit to generate ideas on what to do.Saraki’s media aide, Mr. Yusuph Olaniyonu, said in a statement yesterday that the immediate past president of the Senate, noted with dismay the claim contained in the seventh paragraph of a statement on Tuesday, by Buhari’s media adviser, Mr. Femi Adesina, that ...