Home / Art / Àṣà Oòduà / Ifá naa ki bayi wipe: Osa Alawure (Osa Otura) – Otua Meji

Ifá naa ki bayi wipe: Osa Alawure (Osa Otura) – Otua Meji

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku isinmi ana o, adura wa yio gba, ori buruku koni je tiwa loni o Àse.
Mo nfi akoko yi nki gbogbo onisese patapata kaakiri agbaye wipe aku aseyori odun ifá agbaye o , a ku odun a sin ku iyedun o, emin wa yio se pupo re ninu ola ati idera lase Eledumare.
Gegebi a se mo wípé odù ifá mímó osa alawure lo hu loke olota ni Adó-Ekiti Ekiti state, ti Otua meji naa si hu ni oke itase ni Ile-Ife lodun yi, adupe lowo Òrúnmìlà fun ohun rere to fo funwa.
Awon odu ifá mejeeji naa lo dara, sugbon mo rowa wipe e jeki a tele ilana ti awon odu naa la sile, ki a se etutu ti won so ki a sin pa ofin mo, ifá yo gbewa o.
Laaro yi mo maa koko fi enu ba odu ifá osa alawure to je odu akoko to hu loke olota, ki a to tun maa fi enu ba ti oke itase lojo miran.
Ifá fore nibi ti a gbe ri odu ifá osa alawure, ifá ni awon eniyan yio la lodun yi, ifá ni odun yi ni odun ola awon babaláwo, ifá ni ki a se akose ifá yi ki a fi we ori wa nitori ki idiwo idena baa le kuro loju ona ire wa, ki ire ati igbega baa le wole de funwa.
Ifá naa ki bayi wipe:
Orunmila ni awure
Moni awure
Orunmila ni awure ni alara fi we ori omo tire ti omo tire di olowo

Orunmila ni awure
Moni awure
Orunmila ni awure ni ajero kinosa fi we ori omo tire ti omo tire di olola

Orunmila ni awure
Moni awure
Orunmila ni awure ni owa orangun aga fi we ori omo tire ti omo tire di oloro, ti won kole mole ti won ra ile mole

Moni Orunmila kilode ti o fi nfo bi èdè ti o fi nfo bi èyò? Ewi ile Adó, erinmi lode owo peepee lode asin
Orunmila loun ko fo bi èdè o loun ko fo bi èyò, oni akapo toun loun nbawi wipe ki o lo we ori re ki o baa le di olowo, oloro ati olorire laye
Mo wani toba je biti akapo tire ni nko, kini nkan to maa fi se ti yio fi di olorire laye?
Oni ki o lo ni ewe alukerese, ewe ajé, ew akinsa, ewe ire ati eyele funfun ki won maa fi se sise ifá fun, maari maa mude oni ori akapo yio di ori owo, ori orò ati ori ire gbogbo laye o.

SISE RE: Ao gbo awon ewe wonyen sinu Omi ao pa eje eyele funfun yen sinu agbo naa ao gbaye ifá naa si ao fi fo ori wa toba si je wípé ose ni a fe fi se, ao pa eyele yen sinu abo kan ao gba eje re ao wa gun ori eyele ati awon ewe yen papo ao gbaye ifá naa si ao maa fi we ori nikan, nire ba de.
Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wipe eledumare yio bawa we ìsé ati òsì ori wa danu, ori buruku koni je tiwa, ao jeeyan laye o, awure yio je funwa o aaaseee.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

masoyinbo

#Masoyinbo Episode Seventy-three: Exciting Game Show Teaching Yoruba language and Culture