Ìṣe èèyàn ,ìṣe ẹranko, Ìjàpá tó wà ní ààfin Ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́ Alàgbà ti papòdà lẹ́ni ojilelọọdunrun ọdún ó lé mẹrin lóke eèpẹ̀ .
Fẹ́mi Akínṣọlá
Toyin Ajamu, to jẹ akọwe agba ni Ààfin Kabiyesi Ṣọun ti ilẹ Ogbomọṣọ ti bùn ún akọ̀ròyìn gbọ́ pé ijapa naa ti apele rẹ n jẹ Alàgbà jade laye lẹyin aisan ranpẹ.
O ni nǹkan bi aago mọkanla abọ owurọ yìí ni ọlọjọ de ba a.
Ajamu ṣalaye pe, idi ti wọn fi n pe ijapa naa to sílẹ wọ ní Alàgbà jẹ nitori ọjọ ori i rẹ.
O tẹsiwaju pe erongba ilu Ogbomọṣọ ni lati gbe iyoku ara ijapa ọhun si gbagede, ti gbogbo eeyan yoo si le ma wo o nilẹ yi ati loke okun.
Ajamu ni ijapa naa ti gbe ni aafin Ṣọun fun ọpọlọpọ ọdun,
orukọ rẹ ni Alagba.O ni awọn òṣìṣẹ́ lati aafin Kabiyesi to n tọju oun nikan. Oṣiṣẹ meji tabi ju bẹẹ lọ lo n tọju u rẹ. Lati kekere ni àwọn kan ti n tọju rẹ ti wọn si dagba sẹ́nu ẹ.
Baba Kabiyesi oni to jẹ Jagunjagun lo pade rẹ leti igbo to si mu u bọ wale latoju ogun.
Gbogbo ounjẹ ti eniyan n jẹ loun naa n jẹ to fi mọ eso bii;Ibẹpẹ, Ọpẹ Oyinbo, ,Ọgẹdẹ. bakan naa, o n jẹ amala, irẹsi, dodo atẹwa ati bẹẹ bẹẹ lọ. Akọ̀ròyìn Owurọ rii gbọ pé ijapa naa ti inagijẹ rẹ n jẹ Alàgbà, ti di gbajúgbajà ,irawọ ọsan ti okiki i rẹ si tan tayọ ilu Ogbomọṣọ debii pé, wọn n wa sabẹwo si Alàgbà ,lati àwọn ilẹ okeere,nipa bẹẹ Alàgbà ti mú okiki ba ilu Ogbomọṣọ .