Home / Art / Àṣà Oòduà / Ilé-ìwòsàn àwon ará Sokoto .

Ilé-ìwòsàn àwon ará Sokoto .

Ilé-ìwòsàn àwon ará Sokoto .

Ìyá yí pọ̀
Ó ju omi òkun lọ
Èdùmàrè
Ìwọ tó o dá Ráábí aláṣọ
Dákun má gbàgbé Ráábí eléwé
Èdùmàrè ṣàánú mi
Iná tó ń jó tálákà ní Nàìjíríà
Ó dájú pé ó ju ti ọ̀run àpáàdì lọ

Dákun gbà wá
Agbára wa kò ká wọn
Ìwọ lo ni wá
Sátánì ló ni àwọn
Ìwọ lọ̀gá bàbá wọn
Sátánì ni kó o fi ṣe wọ́n
Kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní í sìnse bí ọmọ ewúrẹ́
Kí ayé wọn bàjẹ́ bí ọmọ adìẹ tí ọkọ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀
Ojoojúmọ́ ni agbálùmọ̀ ń ṣòfò ọmọ
Bí ẹ bá bígba ọmọ
Ọwọ́ igbá nigbá fí í gbé kólòbó ṣin
Gbogbo owó ìlú tí ẹ ti kó jọ
Kó di ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́

Dákun Èdùmàrè
Rán aláàánú sí wa ní Nàìjíríà
Agbára rẹ kúkú ká wọn
O ò sì kúkú bá wa pa wọn run lọ́wọ́ kan
Kó o bá wa yan àwọn èèyàn ọlọ́kàn bí i tìrẹ
Èdùmàrè
Gbọ́ àdúrà yí
Mo gbàdúrà
Lórúkọ Èdùmàrè tí í gbọ́ ẹkùn ẹni tí aráyé ń rẹ́ jẹ
Jésù Olúwa wa
Lágbára Ògún Lákáayé
Ọlá Allahu ọba ọ̀kan ṣoṣo

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti