Home / Art / Àṣà Oòduà / ÌȘẸLẸ̀ INÁ NÍ BÁGÀ

ÌȘẸLẸ̀ INÁ NÍ BÁGÀ

Hàáààà!!!
Iná ooooooo.
Iná pupa bẹ́lẹ́ńjẹ́.
Bẹ́lẹ́ńjẹ́ bẹ̀lẹ̀ǹjẹ̀ bẹ́lẹ́ńjẹ́.
Bẹ́lẹ́ńjẹ́ pupa arańta.
Iná gorí òrùlé tán;
Ó wá fẹjú kẹkẹẹkẹ.
Ìpínlẹ̀ Èkó gb’àlejò iná ńlá.
L’ágbègbè Òjòdú Bágà.
Ó kọjá ohun a le máa f’ẹnu sọ.
Iná ṣe bẹ́ẹ̀, ó búrẹ́kẹ́.
Iná ńlá ọmọ ọ̀rara.
Lónìí ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oșù kẹfà,
Ọjọ́ burúkú Èșù gb’omi mu.
Ó ș’ojúù mi kòró lọ́jọ́ à ń wí.
Adániwáyé ló kúkú kó mi yọ.
Ọba-òkè kì í yọni ká gbọ́ fótí.
Olódùmarè o mà ṣeun ṣeun.
Àfi pàrà!
Iná ló șẹ́yọ.
Bí eré bí àwàdà,
Bí àwàdà bí eré.
Ó di bùlàbùlà,
Iná ń jó kíkankíkan.
Ọmọ ọ̀rara ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń jà bí àrìrà.
Ọkọ̀ elépo ló ṣe sábàbí.
Atólúgbokùn,
Ọkọ̀ tí í gb’ọ̀nà kan kan-an kan.
Afàyàfà tí í da títì láàmú.
Òhun ló șokùnfàa làlúrì.
Ẹgbẹlẹmùkú ẹ̀mí ló șègbé.
Orí kúkú ló kó mi yọ.
Ọkọ̀ tó jóná nínú ìșẹ̀lẹ̀ ọ̀hún,
Kò lè dín láàádọ́ta.
Àìmọye ni dúkìá tó șòfò dànù.
Ká tó wí,
Ká tó fọ̀.
Súnkẹrẹfàkẹrẹ ti gbàlú pitimu.
Mo jẹ́rìí àwọn ọlọ́kọ̀-èrò l’óde Èkó.
Bí ọgán,
Wọ́n ti gb’ówó lórí ọkọ̀ọ wọn.
Lát’orí igba náírà,
Wọ́n sọ ọ́ di náírà lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.
Ìyẹn bẹ́ ẹ bá fẹ́ ti Gbàgádà dé Ìbàfò.
Wàyí o.
Gbogbo ẹni ọ̀rọ̀ ọ̀hún bá kàn,
Èdùmàrè bá wa rọ́ wọn lójú.
Àwa tí ‘ò kàn náà,
Aláùràbí má fi wá ṣe gẹ́gẹ́ ibi.
A ‘à níí ṣe kòńgẹ́ ìjàm̀bá.
L’áșẹ lọ́wọ́ Olúwa Ọba.
Ká má rìn lọ́jọ́ ebi ń pọ̀nà;
Ká má rìn lọ́jọ́ ọ̀nà ń pebi.
Dáàbò Rẹ bò wá,
Ọba t’íșọ́ọ Rẹ̀ kì í yẹ̀ gèrè

Send Money To Nigeria Free

About Awoyemi Bamimore

x

Check Also

Ogbè kànràn

Odù, “Ogbè kànràn” cast for today’s Ọ̀sẹ̀ Ifá

Looking at the Odù, “Ogbè kànràn” cast for today’s Ọ̀sẹ̀ Ifá, I can advise that Ifá shouldn’t be just decorations but served diligently having sacrificed a lot including huge money to acquire it. You should count yourself lucky that you possess an inestimable treasure. Your dedication to Ifa shall never be in vain. Just listen to the stanza as said. Omi igbó ní ń fojú jọ aróOmi ẹlùjù ọ̀dàn ní ń fojú jọ àdínÈkùrọ́ ojú ọ̀nà ó fi ara jọ ...