Home / Art / Àṣà Oòduà / ITAN ORANMIYAN BABA NLA GBOGBO YORUBA AWON EYA TO WA NILE TABI ORILEDE ODUA

ITAN ORANMIYAN BABA NLA GBOGBO YORUBA AWON EYA TO WA NILE TABI ORILEDE ODUA

ITAN ORANMIYAN BABA NLA GBOGBO YORUBA
AWON EYA TO WA NILE TABI ORILEDE ODUA
Loni opo enia mo nro pe gbogbo awa ti awa ni ipinle mefa yi Oyo, Osun, Ogun, Ondo, Ekiti, Eko pelu ipinle Kwara to nka ara won mo ara ipinle Hausa ni o nje Yoruba, ko ri be o, eya kan ni Yoruba nile Odua bi Ekiti se je eya kan ti Egba naa je eya kan be pelu ni Awori naa je Eya kan pelu, koda awon Egun to wa ni badagiri leko ko ba awon omo Odua tan rara (e lo wo Itan Badagiri)
Ki oro ba le ye wa dada e je ka salaye ohun to nje eya fun wa, eya ni ohun to ya lati ara odidi nkan kakari agbaye si ni eya po si, Odua ni baba nla gbogbo eya to wa ipinle mefa yi pelu Kwara sugbon gbogbo wa koni Yoruba. Eya to ya lara Odua le ni merindilogun ti olukulu si mo baba nla re bi eya Yoruba se mo pe Oranmiyan ni baba nla won. Odua lo so gbogbo won po akojopo awon eya yi lo wa nje orilede iyen ni ibi ti won ti nso ede to sunmorawon, iyato diedie yio mo wa nibi ede siso latari alafo ona jinjin to wa larin won, sugbon ti enia ba fi ara ba le yio si gbo ohun ti ede kan nba ede keji so.
ORUKO AWON EYA ORILEDE ODUA
OWU
EGBA
YORUBA
IFE
EKITI
IJEBU
EGBADO
SABE
ONDO
KETU
IJANA
IJESA
IGBOMINA
AWORI
EPO
IBOLO
A o ri pe gbogbo awon eya yi lo gba pe omo Odua ni awon bi won si ti wa saaju ki awon Oibo to wa mu ile Odua sin nu, ni odun 1919 ni awon Oibo pe ipade gbogbo awon Oba ati awon ekan lorile Odua lori oruko ti gbogbo omo Odua yio ma je ibe ni won ti fi enu ko lori Yoruba ti opo awon enia ti mo gbogbo omo Odua si sugbon Ooni Ile Ife Oba Ademiluyi Ajagun (1910-1930) tako pelu alaye pe yio pa oruko eya to ku re, o duro lori ki a mo je omo Odua dipo omo Yoruba. Sugbon ni kehin Ooni Ademiluyi papa gba bi oruko Yoruba to je ti eya kan se di ti gbogbo eya to wa lorilede Odua nu.
ORANMIYAN ODEDE
Opo awon ti won npa itan loni ni ko mo itumo Oranmiyan to wa je pe alo lasan ni won npa, opo ki ti se iwadi Kankan ti won ba ti ka iwe itan kan awon naa ti di opitan nu, won o ni se iwadi Kankan lori iwe ti won ba ka tabi itan ti won ba so fun won, koda itan ti elomiran ba gbo ninu oko lodo ero ti won jo wo oko ti di itan nu.
Isele kan lo fa oruko Oranmiyan, Okanbi je omo Kankan soso to gbehin Odua nitori opo awon omo re ku tan loju aye re nigbati o wa bi awon onimimo won je ko ye pe ila to nko awon omo re lodi si iseda Ile Ife to wa bi kose ko Okanbi ni ila niyi, Okanbi si dagba o fe iyawo awon iyawo re si bi omo fun lehin naa lo wa ri omobirin arewa kan o si ba soro ife omobirin yi si gba lati fe Okanbi sugbon nigbati Odua naa ri omobirin arewa yi oju re wo, o wa bi Okanbi pe se o ti ba omobirin na ni ajosepo Okanbi sini oun e de ibe rara bayi ni Odua se fe omobirin yi to si loyun a mo nigbati o bi omo okunrin omo yi wa je alawo meji lati ori de le, apakan je funfun apakeji je dudu, Odua je enia funfun nitori Sudan to ti wa je ara eya funfun sugbon Okanbi je enia dudu nitori awo iya re to je enia dudu lo mu. Nigbati Odua ri omo alawo meji yi o wa pe Okanbi omo re o si wi fun pe, “Oran mi yan ju bayi pe awa mejeji la jo de be” o to ba ruju ni Yoruba npe ni Oran nitori Odua fura tele mo pe omo oun ti ba omobirin naa ni asepo tele, bi won se so ni Odede nu sugbon Oranmiyanju ni Odua mo npe to yi pada di Oranmiyan.
YORUBA
Kiise bi won se npe oruko yi Yoruba loni ni won npe nikan bi egberun odun sehin ede awon ara ile Sudan ni nitori ile Sudan ni Odua ti wa kiise Meka ni Saudi ati Egypt bi opo awon opitan se so, iwadi ijinle to fi ese mule je kan mo pe awon iran yi si wa ni Sudan di oni. Yariba ni won npe Yoruba tele , iran yariba si wa ni Sudan di oni. Odua pelu awon omo iya re meji to je egbon re lo jo kuro ni Sudan awon naa ni awon eya Boronu to je Beriberi ati eya Gogobiri (Gabari) ni Oke Oya ti won wa larin awon Hausa, di oni Yaribawa ni awon Beriberi to wa ni ipinle Nasarawa ti Lafia je olu ipinle naa npe Yoruba, a o ri pe WA ti won fi kun Yariba-wa naa ni won fi kun Nasara-wa (ise nlo lowo lori itumo ati ohun ti won mo nlo WA yi fun) awon miran a tun mo pe Yoruba ni Beribe ni Oke Oya, lati ara titun oro se lo so di Yoruba.
Itan je ka mo pe ajose po wa larin awon eya meteta yi dada, lehin opo odun ti awon baba nla won ti ku ti won si ri pe, awon o fe mo ara won lokan mo ni won ba se pasiparo awon nkan isura ati isura to je ere ide, idi niyi ti ere Oriolokun Ajana Oro ( ohun ni opo awon alaimokan mo npe ni ere Odua) fi ni ila awon Boronu loju. Sugbon ti iwadi lori lati se ayewo DNA larin awon eya meta yi ba wa ye yio tunbo fi ododo han, a ni lati se fun awon enia ogorun kokan larin awon to je idile Oba eya meteta. Sugbon eri kan pere ti a si le fi idi oro yi mule bayi ni ti ila to wa loju ere Oriolokun to wa je ila awon Boronu.
ITAN ORANMIYAN
Bayi ni Oranmiyan se je alawo meji omo, eyi wa je ki awon enia mo beru re nibikibi to ba lo kosi ohun to nba Oranmiyan leru afi ohun ti eru Oranmiyan to je alawo meji yio mo ba, nigbati to pe ogbon odun o legun lo ilu Benin o si je olori won ni o wa fe omobirin oloye kan to je Ego, omobirin naa si bi omokunrin fun won so ni Eweka iwadi je ka mo pe ogbon odun ni Oranmiyan lo ni Benin. Nigbati Odua ku won ranse pe Oranmiyan o wa fa akoso Benin le Eweka lowo, apakan itan tun je ka mo pe kiise Eweka nikan ni Oranmiyan bi si Benin sugbon eyi to gbajumo ju nipe Eweka nikan ni. Nigbati o de Ile Ife awon egbon re yan lati je Olofin (Olofin ni won nje ni Ile Ife nigbana kiise Ooni) nitori omo enia meji ni iyen Odua ati Okanbi (Okanbi ku ki Odua to ku) bi Oramiyann se je Olofin Ile Ife nu o wa pe awon egbon re pe ki won lo te ilu miran ko mo je pe oun aburo won ni yio mo pase fun won kosi eni to fe kuro ni Ile Ife ninu won nikehin Owu to je agba to si je obirin lo te ilu o si so oruko re ni Owu, o si je Olowu sibe ( gbogbo orile Owu ati ilu Owu ti Owu tedo ti di ara ilu Ibadan loni) bi Ake naa se lo te ilu tire nun to si so ni oruko tire naa bi ti egbon re Owu oun naa si di Alake leyi to tumosi eni to ni ilu Ake (ilu Ake akoko yi naa ti di ara ilu Ibadan lo ka itan Ibadan) be gege ni gbogbo won se lo te ilu won.
Sugbon awon opitan mo nse asise nibi oruko awon omo Okanbi oruko oye ni won mo fi npe won dipo Oruko won gan Owu ni oruko Olowu ni oruko oye, Ake ni oruko Alake ni oruko oye re, Ketu ni oruko kiise Alaketu Alaketu je oruko oye. Popo ni oruko kiise Onipopo, Saabe ni oruko kiise Oni Saabe, Orangun sini Oba Ila, awon opitan je ka mo pe ara awon Ekiti ni won ka ilu Ila mo nigba lailai sugbon a ti se iwadi ijinle le lori ka to ko itan ilu Ila Orangun ao ti se iwadi naa dada. Owa Obokun to te Ilesa je aburo Oranmiyan lati ara iya kanna a mo boya Odua wa ju iya Oranmiyan sile fun Okanbi ni boya Odua lo si bi Owa Obokun fun, sugbon eyi to se gbamu nipe aburo Oranmiyan lo je.
Lehin ti orile Odua ti fe si Oranmiyan wa pe Adimu to je olotoju isura Ile Ife, Adimu yi je omo oluwo (oluwo ni eni ti won ba fe pa bo orisa) omobirin kan lo gba okan lara Olobatala leti to si wa je ese nla, Obatala ni Odua ba ni Ile Ife larin awon onilu Obatala gan ko lo tun te Ile Ife amo o ti nse olori ki Odua to de, oran obirin naa wada waala sile papa nigbati won gbo pe oloyun, nikehin won gba pe ko bi omo inu re tan ki awon to wada ejo iku fun pelu adeun pe awon Olobata ni o ni omo naa ti won ba gba pe ka won mo pa ti yio fi bi omo lehin to bi omo re, won pa lehin to bimo awon Olobatala gbe omo naa won si so ni Adimu nitori ija to waye larin tani yio ni ni omo naa boya oko re ni tabi awon igun Odua tabi igun Olobata. Nigbati awon enia ri pe omo naa dagba to tun wa je eni to mo nipa Orisa Obatala won o wa mo pe ni Adimu Omo-Oluwo-Ni. Adimu yi ni Oranmiyan wa pe lati ko itoju isura Odua le lowo lati mo mu oju to bi Oranmiyan se tun ranse pe gbogbo awon egbon re lati lo be awon ibatan won to wa ni Oke Oya wo nu, nigbati awon enia gbo pe Adimu ni Oranmiyan yan ni alamojuto won so pe “ Adimu la” iyen nipe Adimu ti di olola bi Adimu La se wa di Adimula niyi oriki ni Adimu. Bayi ni won se lo Oke Oya ti won si ko ebun pupo dani lo nigbati won npada bo ni ni Oba tapa fi omo re obirin fun Oranmiyan ni aya, o wa gba Oranmiyan ni yanju ki iyawo re bi omo ko to ma tesiwaju ninu irin re. idi ti Oba Tapa fifi omo re fun Oranmiyan nipe alujonnu lo pe nitori awo re o si ro pe, ti o ba bi omo alawo meji bi re lo ma bi lati wa ri omo naa lo se ni ki Oranmiyan duro, bayi ni awon egbon re se pada si ilu won ti o si duro lodo ana re.
Ni ojo ti Ejide Torosi bimo naa lo ku, o dun Oba Tapa ati Oranmiyan nigbati won gbo pe Ejide ku bi o se bimo tan Oba Tapa si so omo naa ni Sango Oranmiyan si so ni Olufihan nitori o papa mo pe o fe mo bi Oranmiyan se je lo se fi omo re fun. Oba Tapa wa gba Oranmiyan nimoran lati lo te ilu tire bi Oranmiyan se lo duro ni agbegbe Katunga nu to si te ilu sibe Eyo ni won koko npe ko to wa di Oyo, ibi to te ilu si je ile to dara fun ise agbe o tun wa je oju ona ti awon to nse karakata kakari ile enia dudu mo ngba koja eyi wa je ki ilu naa tete mo kun awon egbon re naa wa fi awon enia sowo si lati mo gbe pelu re, lehina lo wa pase fun aboru re lati lo te ilu ti e to nse Ilesa. Oranmiyan ni Oba Yoruba akoko ni Oyo o ti bi Ajaka ko to wa te Oyo.
DIDA ESO SILE
Oranmiyan lo da Eso sile awon ni won si mo nso Oranmiyan adorin ni gbogbo won akoni enia to je omo ilu ni won mo yan lati je Eso kiise oye ajewo (baba si omo) won si pin won si mewa ti awon mesan yio si wa labe eni kokan sugbon laye Alafin Ajagbo ni won wa da oye Are Ona Kakanfo sile ko mo je olori Eso lapapo. Oye ogun ni Eso awon ni won si tele awon Oyo Mesi koda won mo npe awon Eso ni Iba, awon Eso gbodo koju ohunkohun to ba fe ba Oba koda ko je iku, idi oriki Eso ti won mo nki won niyi
Ohun meji lo ye Eso
Eso ja o le ogun
Eso ja o ku sogun
Eso ki gba ofa lehin
Eso to ba gba ofa lehin
Ojo lo se
Ewo ni ki Eso ku ki won wa ri pe ehin ni ofa ti ba. Ilu Oyo kun dada itan si je ka mo pe Oranmiyan lo le ni ogbon odun ko to wa lo be Ile Ife to nse ilu re wo papa egbon re Owu si moyo lenu latari awon Igbo to nyo Ile Ife lenu nigbati Oranmiyan de kia o gbogun ti awon Igbo o si gbe ogun duro ti won nikehin won se adehun pe awon o tun ni gbogun wo Ile Ife mo laialai. Itan pe Moremi fi omo Ela Oluorogbo kansoso jeje lodo omi Esinmirin je ipa alo po mo itan. Sugbon o wa le je pe eyi ti sele ki Odua to wa gba akoso Ile Ife sugbon Oranmiyan to ko won loju ti a ba si wo bi won nse ko ile ni Ile Ife nigba lailai ao ri pe eto iloro si iloro ni kiise Agbole ti awon ilu Ile Yoruba igba laialai yoku nko.
Lehin to segun igbo tan o wa tun fakoso ilu le Adimu lowo o si lo lati sure fun awon omo re o wa bere lati odo Eweka lehinna o ya odo Owa Obokun aburo re ko to wa fi Ori le Oyo, nigbati o de Oyo o ba Sango to wa wa lati ile Tapa ni Oyo, o sure fun Ajaka ati Sango o si so fun Sango ki o mo pada si ilu Tapa mo nitori Oyo yio tobi yio si ni oruko ju ilu baba iya re lo atipe Sango ni ko je Oba lehin Ajaka lehina lo wa pe gbogbo awon enia pe enikankan ko gbodo mu isura Kankan jade ni Ile Ife, o si fi ase lele pe ti won ba ti fe je Oba ni Oyo ki won lo mu ida oun lati Ile Ife wa ki won fi le Oba lowo lehin naa ki won da pada si Ile Ife, lehin eyi lo sure fun gbogbo omo Odua o si pada si Ile Ife itan so pe oju ona lo ku si apa kan ni Oyo lo ku si omiran ni o de Ile Ife ko to ku atipe ibi ti won sin si ni Opa Oranmiyan wa ni Ile Ife di oni, sugbon awon to fara mo pe Oyo lo ku si ni irun ori re ati ekanna owo pelu ti ese ni won ge ti won si sin si Ile Ife nitori be ni won se mo nse fun eni to ba ku si ona jinjin won si fi ara mo pe oun ni Oba akoko ti won koko sin si Oyo. Kiise oyo toni o koda ki se Oyo Igboho nitori Oyo kerin ni toni ti Alafin Atiba gba lowo awon omo Oja to te Ago to wa di Oyo loni. Sugbon to ba je Oyo ni Oranmiyan ku si to si pase ki won gbe oun lo Ile Ife awon omo re ni lati se be, nitori nigbati Are Latoosa ku si ogun Ekiti-Parapo fun odun meta won gbe oku re lo Ibadan lehin odun kerin ni won to sin, won mo ona ti enia fi ngba se oku lojo bi ti awon ara Sudan ati Egypt. Bakanan ohun to tun le je ka gba pe won le ge ori Oranmiyan nikan wa si si Ile Ife ni, nigbati Eweka to je Oba Benin ti nse omo Oranmiyan ku ori re ni won ge wa sin si Ile Ife titi di igba ominira Naijiria lowo awon Oibo amunisin be ni won nge Ori awon Oba Benin wa si sibi to je Orun-Oba-Ado lati je pe orirun Eweka ni o sun ati aromodo re, yato si alo ti Oba Benin kan npa nibi odun meje sehin pe eru awon kan to sa ni Benin lo wa te Ile Ife oun sini Odua.
Iro nla ni eyi bawo ni won se le lo mo sin ori Oga si odo eru re, gbogbo itan to fi ese mule gba pe Oranmiyan ni baba nla awon Oba Benin. Ti Oba Benin ba si wa Ile Ife ti Oba Alafin Oyo naa si wa Apa otun Ooni ni Oba Benin yio joko si ti Oba Alafin yio si joko si apa osi lati le fihan pe Egbon ni Oba Benin je si Oba Alafin Oyo
OPA ORANMIYAN
ORI OLOKUN
Opa Oranmiyan je ami kan ti ise iwadi kun ara re fun awon oluwadi ese bata mejila ni Opa yi fi ga, won wa kan iso mo ara opa yi lati se onka tabi ewa apapo onka yi je etalelogofa (123) ona ti won gba to onka ara Opa Oranmiyan je meta awon opitan je ka mo pe, lati owo isele de arin je odun ti Oranmiyan lo ko to je Oba Benin, onka apa otun ntoka si odun to je Oba Benin tarin nkota si Igba to fi je Olofin Ile Ife nigbati ti apa osi ntoka si odun to fi je Oba Oyo, ti enia ba si gbogbo onka yi po a wa mo pe odun metalelogofa (123) ni Oranmiyan lo laye, emo to wa lara Opa yi ni bi awon onka to je irin se le wole si ara apata ko si duro lati bi igba odun ti iwadi ti bere lori Opa yi ko ti si enikan to le so pe o ti ri alaye lori Opa yi, opo itan ti awon ara Ile Ife nso nipa re ni iwadi ijinle ko si gba wole loni. Sugbon iwadi ti mo nse lowo nipa Opa Oranmiyan je ki mo pe ojo Opa yi ju ti Oranmiyan ti won ni oun lo ni Opa yi lo, mo si duro lori nkan meji nipa re akoko o le je pe asise wa lara igba ti Odua ti de si Ile Ife nitori itan ni ko ti ju egberun odun kan lo sugbon ti Opa si ti loo to egberun meta si egberun marun, ekeji o le mo je pe Oranmiyan lo ni Opa yi ko je pe o ri he tabi ki won fun gegebi ebun fun enia Pataki tabi ki o fi ogun gba, nitori ni Eshie ni ipinle Kwara awon okuta ti won fi gbe enia po ni ibe nigbati won ri awon ere yi, won ba won ni oju kanna ti won ko won si apapo gbogbo won si je egberun kan abo.
Eyi yio wa je ka mo pe o sese ki awon ara Ile Ife ri Opa yi lehin ti Oranmiyan lo tan ki won wa fi sori re tabi ko je pe Oranmiyan gan lo ti ri Opa yi, sugbon egberun odun meta si merin wa larin Opa yi ati Oranmiyan lori itan to nbe lori onka awon Oba Ile Ife, ti a ba si wo abo iwadi ti Oibo Frank Willet lori awon afoku Ikoko ti won fi se titi to wa ni Yemoo, iwadi je ka mo pe o ti le legberun meta si marun ti awon Ikoko afoku yi ti wa nibe Yemoo ti won lo ni ibe je Iyawo Obatala ti Odua ba ni Ile Ife. Ko to wa kan Titi Luwoo lehin Odua, Okanbi ati Oranmiyan si Oba Luuwo se awon titi yi ko to wa kan titi interlock ti awa wa sese nse loni (lo ka iwe mi Titi Luuwo). Iwadi mi nlo lowo nipa Opa Oranmiyan yio gbe mi de ile Hausa, Sudan ati Egypt lati le tan imole si Opa yi ati awon nkan isura miran to wa ni Ile Ife.
Ju gbogbo re lo igbagbo awon enia Ile Ife di oni nipe onkan odun ti Oranmiyan fi je Oba ni ilu meteta ni won fi ka. Lehin onka to je irin won tun wa gbe okuta meji si owo arin leyi to tumosi awo meji ti Oranmiyan ni. Opa Oranmiyan nse afihan isokan ti Oranmiyan fi sile ko to kuro laye ni. Laisi je pe Oba ba de idi re ni Ile Ife Ooni ko ti ni ase lenu, ewo ni fun enikeni lati bura eke nidi Opa Oranmiyan.
AWON AFOKU IKOKO YEMOO
BIBE OPA ORANMIYAN WO
Ofe ni wiwo Opa Oranmiyan ni Ile Ife fun enikeni nitori gbangba lo wa koda ki enia to wole sinu ogba to ni enia yio ti mo ri nitori pe o ga soke dada ni ese bata mejila. Amo ti enia ba fe to dada ko koko lo National Museum to wa ni Afin OOni Ile Ife yio gbo alaye nipa re ati opo nkan miran ti wa nibe, titi di odun yi adota naira pere ni enia fi nwo isura isenbaye ni Afin Ile Ife.

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

masoyinbo

#Masoyinbo Episode Seventy-three: Exciting Game Show Teaching Yoruba language and Culture