Home / Art / Àṣà Oòduà / Ìwúre Òṣù Tuntun
iwure

Ìwúre Òṣù Tuntun

Bí ÒṢÙ bá yọ loke terutọmọ niiri,
omi ajipon kiiru, ninu ÒṢÙ kẹfa yi aye gbogbo wa yio toro minimini, bi Ọgẹdẹ ba pọn ará aa dẹẹ, ara oni ni emi àti Ìwọ oluka àtèjìṣẹ mi yi, àtijẹ atimu koni jẹ inira fún wa, tọtuntosi ni ẹiyele fi nko ire wale, ire owo ire ọmọ ire ile tuntun ire ọkọ àti aya tuntun yio wọle wa wa, nibikibi ni origun mẹẹrẹrin ayé, tí àwọn ooloore wà wá, Ọlọrun tio ṣé àwáàrí Aake nínú omi, nínú ÒṢÙ yi ooloore wà yóó wá wá rí, yio sí fí ire wá l’ewa lọwọ,
Kọkọrọ Ayọ rẹ yio tẹ ẹ lọwọ,
Bí akeregbe bá fọ ŃṢE nii dẹ̀hìn lẹ́hìn odo, ori buruku yio dẹ̀hìn lẹ́hìn gbogbo wa, Ipọnju, aṣeeri, amubọ, ijakulẹ, afaa’to, idiwọ, idena, àti ẹti yio dẹ̀hìn lẹ́hìn wa, ìbànújé, ẹkun ajọsun, ẹkun adasun, ẹkun asunrin koni jẹ ti’wa, àṣẹ oooo,
ogun idile, ogun ile binukonu, ogun ibi ìṣẹ, ogun arinako nínú ÒṢÙ yi Ọlọrun yio ṣẹ wọn wọlẹ pátápátá nínú aye wá àmìn, Ohùn Ayọ tí yio mú inú wá dùn tí ọpọlọpọ ènìyàn yio bawa se ajọyọ rẹ nínú ÒṢÙ yi Ọlọrun yio ṣé fún wa nínú ÒṢÙ tuntun yìí iṣẹlẹ iyanu Ayọ tí kó i ti ṣẹlẹ rí nínú ẹbí wá yio ṣẹlẹ nínú aye emi àti Ìwọ oluka àtèjìṣẹ mi yi, tí àwọn ènìyàn yio fí máa fí orúkọ tuntun pé wa. Àmìn.
Ọmọ wá kóni Kú,
Ọkọ wá kóni Kú,
Aya wá kóni Kú,
Ojú kiipọn iṣin ki o má LÀ afaila ọjọ bí ọjọ bá tí LÀ gbogbo wà ni láti LÀ, ṣẹkẹrẹ kì bá wọn rode ìbànújé, ìbànújé oni kàn wá lagbara elédùà, àṣẹ gun. Ao ṣégun oṣo ilé àti ajẹ ode, ao rẹyín odi.
Otiri bẹẹ, nítorí bẹẹ lewurẹ nke kó’ni yí padà. NÍ opin ÒṢÙ kẹfa yi ao Jọ gbé igba Ọpẹ Àmín oooo ooo

A ku ÒṢÙ tuntun o, yio tuwa Lára ooo koni le koko mo wa Àmín àṣẹ oooo.

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti