Home / Art / Àṣà Oòduà / “Ko saaye fun Toll-Gate bayii” – Egbe Akoroyin tiluu Eko
lagos

“Ko saaye fun Toll-Gate bayii” – Egbe Akoroyin tiluu Eko

E gbe akoroyin, Nigeria Union of Journalists eka ti ilu Eko, ti gbe atejade kan jade eleyii to n ro ijoba apapo lati se atunse si awon oju ona masose wa ki won to ronu a ti da Toll Gate pada si aarin ilu.
Nibi ipade eleyii ti egbe naa se to waye l’Ojoru ose to koja yii, eleyii ti won fi kase odun 2015 nile ni alaga egbe naa, Ogbeni Deji Elumoye ti n buwo lu atejade ti won fi sita naa.

“Ti ijoba ba fe da awon enu iloro igbowo lowo awon awako pada, o se pataki ki awon oju ona wa wa ni ipo ti o mu igbokegbodo oko wa ni irorun,” Ogbeni Elumoye fi kun oro re bee.

Ninu atejade egbe naa eleyii to te Olayemi Oniroyin lowo ni alaga egbe naa tun gbe oriyin rabata fun Gomina Akinwunmi Ambode pelu awon ohun elo igbogun ti iwa idaran ni ipinle Eko eleyii ti won pese laipe yii. O ni inu oun dun lati ri oko ofurufu Helicopter, oko oju omi ati aimoye orisiirisii awon ohun elo ti o fun awon osise alaabo lagbara.
Bakan naa lo si n ro awon osise alaabo oju-lalakan-fi-n-sori, Rapid Response Squad (RRS), lati maa lo awon ohun elo igbogun ti idaran naa lona to dara. Paapa julo ni akoko poposinsin odun tuntun to wole de yii.
Orisun: Olayemioniroyin.com

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti