Home / Art / Àṣà Oòduà / Iwulo Ewe To Wa Ninu Aworan Yi Ninu Odu Ifa OGBEYONU,
ogbeyonu - agogo igun

Iwulo Ewe To Wa Ninu Aworan Yi Ninu Odu Ifa OGBEYONU,

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a sin Ku isimi oni emi wa yio se pupo re laye o ase.
Loni mofe ki a mo iwulo ewe to wa ninu aworan yi ninu odu ifa OGBEYONU, ewe yi wulo lopolopo to je wipe o maa ntu aye eniyan ro bi agogo ni, ewe yi si je okan gbogi lara awon ojulowo ewe ifa OGBEYONU ati fun wiwe ifa pelu.
Awon Yoruba maa npe oruko ewe yi ni ewe agogo igun sugbon awa ekiti maa npe ni apari igun lede isedale tiwa.


Ifa naa ki bayi wipe:
Orunmila ni ayétè
Moni ayé wó
Moni eku ni won maa fi se ti aye maa fi gun Orunmila ni ki nse oro eku
Orunmila ni ayete
Moni aye wo
Moni eja ni won maa fi se ti aye maa fi gun Orunmila ni ki nse oro eja
Moni ewure amori kege, agbo abiroro ija wole, elede amapoti nimun tabi elila amagada fifonfifon ni won maa fi se ti aye maa fi gun sugbon Orunmila ni eran lo nwumi nje ti mo fi ndaruko gbogbo awon eranko wonyen oni ki nse gbogbo awon nkan wonyi ni won maa fi se aye to maa fi gun, moni Orunmila mo jewo obun ki o wa daso romi, Orunmila ni bi mo saigbon ti mo saimoran oni semi ko mo wipe akuko adiye, ewe agogo igun, ewe ogungabe…………., igun ni ao fi se ile aye to maa fi gun ni.
Moni motiri moti muwa, oni ógún ógún ni won nsin adé, ógún ógún ni won nsin agbon oni ire aye akapo toun yio gun.
Alaye odu ifa yi nso funwa wipe akapo ti odu yi ba jade si nilati gbe igbese bi ile aye re yio se gun ti yio tuba ti yio si tuse, ifa ni nkan ko lo deedee fun akapo naa, ifa ni gbogbo ona re lo daru mo loju, sugbon ifa gba niyanju wipe ki o se akose ifa yi nitori ki o baa le sawari aye re, ki gbogbo nkan re baa le dara ki ona re baa le gun laye.
AKOSE RE: ao lo awon nkan wonyen kuna pelu eje akuko adiye yen ati ogbe ori adiye naa ao wa gbaye ese ifa yi si ao po po mo ise ifa yen ao fi sin gbere sorun wa yika, eleyi to ba ku ao po mose fun wiwe.
Eyin eniyan mi, mogbaladura laaro yi wipe gbogbo ona aseyori, igbega, ise rere wa to ti wo yio gun pada, igbesi aye wa koni daru lagbara eledumare, ako ni fi inira ati idaamu gbele aye o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

Lati owo Faniyi David Osagbami

ENGLISH VERSION:

Continue after the page break

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

masoyinbo

#Masoyinbo Episode Fifty-One with ‪@yemieleshoboodanuru589‬ #Yoruba #learnyoruba #yorubaculture