Home / Art / Àṣà Oòduà / Odo Iwoyi – 3
yoruba

Odo Iwoyi – 3

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Odo Iwoyi wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.

Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-

“Olootu mo ki yin pupo e ku eto o, e jowo nko mo Yoruba ko daradara, eyi ni ko je ki n le se alaye oro mi ni kikun sugbon e jowo e ba mi fi oye gbe niwonba ibi ti mo koo de.

Omo owo ni mo wa ti gbonmi si omi o to fi sele laarin awon obi mi, ti eyi si se okunfa iyapa laarin awon mejeeji. Odo maami ni mo dagba si, ni akoko yi ile oko miran ni maami wa, tosi je wipe oko maami yi ni mo gbonju mo gege bi baba mi tori bi baba gan ni alagba yi n se si mi koda opolopo ti won wa ni ayika ko mo titi di oni wipe arakunrin yi ko ni baba ti o bi mi lomo.

Maami ko setan lati so ododo oro yi fun mi, sugbon ni akoko ti mo ti balaga ni arakunrin yi pemi, ti won si so opo oro tutu fun mi wipe awon o Setan lati ba mi lokan je sugbon awon fe ki n kan mo okodoro oro ni, lojo yi ni alagba yi je ki n mo wipe awon ko ni baba ti o bi mi lomo.

Leyin eyi ni mo bi maami wipe ta ni baba ti o bi mi lomo gan? Maami sun opolopo ekun ni ojo ti a nwi yi, ti won si wa da mi loun wipe awon setan lati se alaye bi n o se ri baami sugbon awon o le ba mi de ibe tori oru ati osan kii pade, wipe awon o le foju kan baami lae.

Ki n ma fa oro gun mo lo ri baami, ti baami si gba mi gege bi omo, won si wa wi fun mi wipe igbakugba ti mo ba nilo iranlowo awon ki n ma kan si awon sugbon awon o fe ri maami o. Nje ki ni o sele gan baami wipe oro na koja agbara mi wipe ki n menu kuro nibe.

Isoro ti mo wa ni bayi ni wipe osu ikeje odun yi ni igbeyawo mi yoo waye ti baba ati iya mi si gbudo wa nibe, mo si ti ba maami soro lopo igba sugbon nse ni maami yari kanle wipe niwon igba ti baami yoo wa ni ijoko lojo na, awon ko le yoju sibe, beeni baami pelu wipe ti maami yoo ba yoju si ibi ayeye na, awon ko ni lee wa nibe nitori sooso meji ko gbudo foju kan ara won.

Oro yi wa toju sumi, koda gbogbo awon agbaagba ti mo mo ni idile mejeeji ni won ti da soro yi sugbon nse ni awon mejeeji faake kori wipe ayafi ti nko ba fe ki alafia o joba nibi ayeye na. Baami wipe awon setan lati ran mi lowo ni gbogbo ona sugbon awon ko le joko po pelu maami lae, won si wipe koda ti mo ba ni elomiran ti o le joko pelu maami o ba awon lara mu.

Oro na ko wa fe yemi mo, iyen ni mo se ni ki n fi to eyin ojogbon leti ki e la mi loye, iru ogbon wo ni a da soro ile yi?. Se maami ni ki n mu pelu mi ni abi baami? E jowo e la mi loye o”

Hmmmm Oro re o, Eledua o kuku ni je ki a rogun ti yoo gbe wa pamo lojo eye omo wa. Abi iru ki leyi? Eyin oloye eniyan, e jowo e ba wa da soro ile yi o..

Lati Owo Abel Simeon Oluwafemi

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

orisa

The World of the Yoruba Orisa