Home / Art / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Iwure Toni Ki Bayi Wipe..
ifa ni

Odu Ifa Iwure Toni Ki Bayi Wipe..

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Eku ojo meta o, Ogun lakaye yio bawa segun awon ota wa yio si lana ire gbogbo funwa loni ase.
Odu ifa iwure toni ki bayi wipe:
Irete Osa kubu irete Osa kebe, irete Osa kenbekenbe a difa fun Ogun lakaye ejemu oluwanran omo adigirigiri rebi ija lojo to ngbogun re oja ejigbomekun won ni ki o karaale ebo ni ki o wa se ki o baa le segun lohun ki o baa le kérú kérù wa sile, obi meji, ako aja, akeregbe emun, otin isu sisun, epo, iyo, Ogun lakaye kabomora o rubo won se sise ifa fun, nigbati Ogun lakaye maa de oja ejigbomekun o segun awon ota re o keru o si keru wa sile o wa njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe Ogun lakaye yio bawa segun awon ota wa o, yio si lana ire gbogbo funwa, bi odun yi se nlo sopin Ogun lakaye koni fi eran wa yile, omo e ni yio fi wa se koni fiwa se ota e o, ako ni sun ninu agbara eje loni aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.
English Version:

Good morning my people, how was your night? Longtime to you all! Hope your night was great, I pray this morning that Ogun lakaye will make a good path for us and help us to conquer our enemies amen.
Today’s ifa prayer said:
Irete Osa kubu irete Osa kebe irete Osa kenbekenbe cast divined for Ogun lakaye the ejemu oluwanran the son of adigirigiri rebi ija when he was wagging war to ejigbomekun market, he was advised to offer sacrifice, two kola nuts, male dog, roasted yam, palm oil, palm wine, gin and he complied, when he reached the ejigbomekun market he fought and conquered, he returned back home with plenty of goods and slaves he started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.
My people, I pray this morning that Ogun lakaye will help us to conquer our enemies, and make a good path for us, as this year is going to an end may will never swim in the pool of blood and Ogun lakaye will never see us as his enemy amen.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti