Ifá pé òun yóò ṣe oore òjijì fún ọmọ Ogbèyọ́nú tàbí ẹni yòówù tí a dáfá yìí fún. Ifá pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò tó nǹkan nínú òun; pé kó lọ ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ síwájú síi nínú òun Ọ̀rúnmìlà.
Ifá pé kí ó máa ṣèbọ fún òun ní ìgbà kú gbà tí ojú bá ti fẹ́ máa pọ́n ọn fún ire gbogbo pẹ̀lú eku, ẹja àti abo adìẹ.
Òwúùrù (ọ̀pọ̀lọpọ̀) ẹyẹlé àti ẹgbẹ̀rin ọ̀kẹ́ owó ni ẹbọ rẹ.
Àkóṣe /Àtẹ̀ṣé
A ó gùn ún èso ọ̀pọ̀tọ́ díẹ̀ tí ó bá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèrà lára pẹ̀lú ọwọ́ alákẹdun díẹ̀ mọ́ ọṣẹ dúdú, a ó pa ẹyẹlé kan fún ọṣẹ náà, a ó máa fi wẹ̀ lóòrè-kóòrè.
B’áráyé bá ń gan ni
B’árá ọ̀run ò bá gan ni ó tán
A dífá fún Mọ́kànjúọlá ọmọ Ẹlẹ́rìn Șàjéjé
Ìgbà tí ó ń fi omi ojú ṣe ìráhún ire gbogbo
Ẹbọ ni àwọn Awo ní ó ṣe
Ẹbọ rẹ̀ náà dà ládàjù
Ǹjẹ́ Mọ́kànjúọlá ìgbà wo lo d’olówó
Mọ́kànjúọlá ìgbà wo lo d’aláya
Mọ́kànjúọlá ìgbà wo lo d’ọlọ́mọ
Mọ́kànjúọlá ìgbà wo lo d’onílé
Àní Mọ́kànjúọlá ìgbà wo lo d’oníre gbogbo
Òní Ifá ni ẹ bá mi kì
Ọ̀pẹ̀ ni ẹ bá mi yìn
Ẹnìkan kìí mọ̀gbà tí èèrà wọnú ọ̀pọ̀tọ́
Ṣèbí lójijì là á bá ọmọ lọ́wọ́ alákẹdun
Ire ni o!