Ki e to tesiwaju lati ka abala keji iroyin yii, maa royin ki e ka abala kinni na.
Eleyii yoo fun yin ni oye ibi ti alaye naa ti bere. E le ka iroyin naa ninu linki isale yii:
Bi o tile je wi pe ko si akosile kankan eleyii to toka si ojo kan pato ti Obasanjo ko iyawo re akoko, Remi Obasanjo, sile; sibesibe Obasanjo se apejuwe re gege bi iyawo re to ti jawe fun ni kootu ninu iwe itan-ara-eni to gbe sita lai pe yii, My Watch.
Sugbon ninu iwe ti iyawo re naa ko, eleyii to pe ni ” Bitter-Sweet My Life with Obasanjo,” o salaye wi pe Obasanjo gan-an ko lo jawe fo’un, oun gan-an ni oun lo si kootu lodun 1975 lati jawe fun Aremu Obasanjo baba Iyabo.
O se alaye Obasanjo gege bi okunrin to n yan ale ati okunrin to feran lati maa na iyawo re bi eni luso ofi.
Lara apeere iru awon iwa Obasanjo ni eleyii to waye lodun 1968. Ni akoko yii ni Remi loyun omo eleekeji, Busola, eleyii ti akoko ati bimo re si ti sun mole.
Ni akoko yii, ilu Ibadan ni won gbe. Remi o si nile lojo kan ni Obasanjo gbe ale wa le.
Awon mejeeji jo goke lo ninu yara, won si pe gidi gan-an ki won to sokale.
Omoodo ti n sise pelu won nigba naa lo sofofo fun Remi nigba to de. Remi koju oko re wi pe taani obirin ajoji to gbe wole. Kaka ki Ebora Owu salaye ohun to se ninu yara, igbaju-igbamu-ni-kerikeri-n-ba-rode lo fi oro Remi se.
Matthew ko tile wo toyun inu iyawo re, ko to di wi pe o bere si ni ko igbaju olooyi bo aya kan soso to fe nisu-loka.
Ki ni alaye Olusegun Okikiola Obasanjo nipa iyawo re, Remi Obasanjo?
Maa duro nibi lati ma se alaye to ku laipe.
Ire o!