Home / Art / Àṣà Oòduà / ỌJỌ́ NÁÀ RÈÉ BÍ ÀNÁ
NYSC

ỌJỌ́ NÁÀ RÈÉ BÍ ÀNÁ

 

Ọjọ́ náà rèé bí àná.
Bí eré bí àwàdà;
Kánmọ́kánmọ́ l’ọjọ́ ń șí lọ bí ẹyẹ.
Ọjọ́ náà rèé bí àná;
Tá a bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìrìn-àjò ọ̀hún.
Òjòó rọ̀ wọ̀wọ̀.
Afẹ́fẹ́ fẹ́ ilẹ́lẹ́-ilẹ́lẹ́.
Ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ẹ́ m’igi oko dìgbàdìgbà.
Ojúu sánmọ̀ọ́ wá dúdú batakun.
Akọniì mi wá mikàn pẹ̀pẹ̀ẹ̀pẹ̀;
Ó ṣe mí bíi kí n sá padà sẹ́yìn.
Șé t’ebi là bá wí ni,
Àbí tàìní șíșì tó yọ́ lọ́wọ́.
Ṣé t’ișẹ́ àședààjìn ni ká sọ ni;
Àbí ti bó-o-jí-o-jí-mi là bá wí.
K’íșẹ́ ó ga bí òkè,
Ká taari ẹni sí i lára ohun a fojú winá ni.
Ọjọ́ náà rèé bí àná,
Tá a bẹ̀rẹ̀ àgùnbánirọ̀ ní Ẹdẹ.
Ní kùtù hàì,
Àwọn ológun a jí wa tariwo tariwo.
Aago mẹ́ta àbọ̀ láàjìn,
Ni wọ́n kúkú ń jí wa.
Ọ̀pọ̀ a lẹ̀ tíkẹ́tíkẹ́ m’ábẹ́ ìbùsùn,
Ẹlòmíì a lọ farasin sí Mọ́șáláșí.
Àmọ́ șá, lóòjọ́ọ Sójàá jágbọ́n-ọn wọn,
Nìsáǹsá àgùnbánirọ̀ọ́ ru’gi oyin.
Wọ́n wá f’orí jálé agbọ́n gbáà;
Ń’torí ọwọ́ọ pálábáa wọn tó ségi.
Wọ́n sì tún kàbùkù tààrà.
Ọjọ́ náà rèé bí àná,
Tá a jáde nípàgọ́ àgùnbánirọ̀.
Ọjọ́ náà rèé bí àná,
Tí mo d’Ótù-Ifẹ̀;
Níbi ọjúmọ́ọ’re ti ń mọ́ wa.
Ọjọ́ náà rèé bí àná,
Tí mo bẹ̀rẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ ìsìnrú-ìlú sàn-án.
Lẹ́yìn ìgbáradì ọjọ́ díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ológun,
Wọ́n gbé wa raná kèrémí kọ́.
Araa wa wá dá șáșá bí ara ológun.
A sì gbọnraa sìfílíànù dànù.
Ọjọ́ náà rèé bí àná,
Tí mo mú’wèé dé’lé-ișẹ́ OÒDUÀ FM.
Mo wá dúpẹ́ dúpẹ́,
Mo dú pẹ̀pẹ́-òkun mọ́ ọn.
A kì í șọ̀rẹ́ èrò ká yọ̀,
Ó pẹ́ ni, ó yá ni, èrò á re’lé ‘ẹ̀ bó dọ̀la.
N ‘ò le gbàgbé Ilé-Ifẹ̀ láyé.
N ‘ò le gbàgbé Ẹdẹ Mọ̀pó-àrógun.
N ‘ò le gbàgbé NYSC.
N ‘ò le gbàgbé MCAN.
N ‘ò le gbàgbé CHARITY CDS.
Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ dájúdájú;
N ‘ò le gbàgbé OÒDUÀ FM fáàbàdà.
Bí àwàdà bí eré,
Bí eré bí àwàdà,
Àgùnbánirọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ó tẹnu bọpo.
Ẹní kàwé tí ‘ò șàgùnbánirọ̀,
Ohun tó nù wọ́n ‘ò ṣeé máa f’ẹnu sọ.
Ẹní ș’àgùnbánirọ̀ ẹ̀wẹ̀,
Tí ‘ò ṣe t’ìpínlẹ̀ Ọmọlúàbí.
Bí ẹni tí ‘ò ṣe nǹkankan kúkú ni.
Bó o bá șàgùnbánirọ̀,
Bí kì í bá ń ṣe n’Ílé-Ifẹ̀ yù à rọ́ǹgì.

Àgùnbánirọ̀ ọ̀hún dùn,
Kódà ó ní gbọ́ngbọ́n nínú.
Bá ‘à bá lọ,
A kì í dé.
A dúpẹ́ a rọ́jú, a bá wọn lọ.
Gbogbo ọpẹ́.
Gbogbo ìyìn.
Gbogbo ògo;
T’Olódùmarè Ọba ní í ṣe.
Má f’èyí ș’òpin bàbá mímọ́.
Lójú abanijẹ́ onínúnibíni,
Jẹ́ n túbọ̀ tún wàyàmì.
Àmín àṣẹ!

Láti owo…

Ọmọ-ọba Babátúndé Adéṣínà.
Ẹ̀bùnlọmọ Akéwì Akọ̀wé.

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

taniolohun

Esin Ajeji Pelu Ete