Home / Art / Àṣà Oòduà / Olobe Lo Loko Soko-Yokoto
olobe

Olobe Lo Loko Soko-Yokoto

Eto Olobe lo loko soko-yokoto ni o gori afefe bayii,,,,,, Adupe lowo olorun fun abo re lori wa, oba ti o pawa mo titi Di ojo oni, a dagbere ni ijejo, atun dupe wipe eledumare ka wa ye loni.
Lori eto toni ounje aladidun meji ni a o fi ko wa ni eko, awon ounje naa ni iwonyi;- (1).AMALA ATI GBEGIRI
e maa bawa Kalo………
Ounje akoko ni AMALA, Awon ohun ELO ti a o lo fun AMALA wa ti oni ni iwonyi….
ELUBO ISU OMI
Bii a o ti se niyi ooo; -Ipele akoko;-. A o koko gbe omi ka ina, titi ti omi yio fi ho daradara.
Ipele ikeji.;- Leyin eyi, A o bu die kuro ninu omi gbigbona yen, a o yin ina yen sile die, a o ma da elubo yen si diedie, a o si ro papo pelu omorogun wa, a o si ma ro papo titi ti yio fi le, ti ko si ni di Koko.
Ipele iketa.;- Leyin eyi, ti amala yen ba le, a o da omi gbigbona si, ao wa fi omorogun wa da koto si aarin amala wa yen, ki omi yen ba le hoo mo daradara fun iseju marun.
Ipele Ikerin;- Leyin eyi, A o wa ro amala yen daradara titi ti yio fi Dan, ti ko ni si Koko mo, ti yio si see je.
Ipele Ikarun;-. A le pon sinu ora tabi ki a koo sinu abo.
OUNJE IKEJI NI:- GBEGIRI Awon ohun Elo ti a o lo ni iwonyii;-
EWA(funfun tabi pupa)
EPO
IRU
ATA GIGUN
EDE
MAGGI
IYO
Bi a o ti poo papo ti yoo Di odindi ree:- igbese kinni:- A o koko bo ewa wa daradara
Igbese keji:- Leyin eyi, A o gbe ka ina, a o fi omi pupo si, a o si se titi ti yio fi ro daradara
Igbese keta:- Leyin ti ewa yi ba ti ro tan, a o lo papo tabi ki a fi sibi wa foo papo.
Igbese kerin:- Leyin eyi, a o da pada si ori ina, a o fi ata gigun si, a o fi maami, iru, ede, epo ati iyo si, a o gbodo je ki epo yen po ju, leyin eyi, ao fi sile ki o ho fun iseju marun, GBEGIRI ti dele niyen.
A le fi je AMALA PELU EWEDU.
Too a o ni ri ju bayi lo lori eto olobe loloko sokoyokoto toni, emi omo yin, aburo yin naa ni OMIDAN FALADE OPEYEMI WURAOLA
Aye wa fun Amoran, Afikun, Ayokuro ati ibeere,,,,,,,,,, Nje a ri Eni ti o ni ibeere bii.?.?

Falade Opeyemi Cecilia

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti