Home / Art / Àṣà Oòduà / Ọọ̀ni Kò Ṣe Rífín ! (Apá Kìíní Lati Ọwọ́ Daniel Adefare)
ooni-ile-ife

Ọọ̀ni Kò Ṣe Rífín ! (Apá Kìíní Lati Ọwọ́ Daniel Adefare)

Oríadé, ọrùn-ìlẹ̀kẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ajunilọ mo júbà o.
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní “Kíkéré labẹ́rẹ́ kéré, kìí ṣe mímì fádìyẹ” Káláyé tó dáyé, kékeré kọ́ ni Bàbá fi ju ọmọ lọ. Ọọ̀ni kìí ṣe ẹgbẹ́ ọba kọ́ba gẹ́gẹ́ ìtàn ti sọ́ ọ di mímọ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ?
Eégún ilé kò ṣe rífín, òòṣà ọjà kò ṣe é gbálójú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Ọba Ẹnìtàn Adéyẹyè Ògúnwùsì, Ọọ̀ni tilẹ̀ Ifẹ̀ ri. Ẹni tó bá fi ojú di Ọọ̀ni, dandan ni kí àwówó wó.

Eyín funfun báláí ni iyì ẹnu, ẹ̀jẹ̀ pupa yòò ni iyì òòṣà, àpọ́nlé ló yẹ olórí Ọba yoòbá gbogbo kìí ṣe ìwọ̀sí.
Ohun ti Ọba Rílíwànù Akiolú, Ọba Èèkó ṣe sí Ọọ̀ni kò dara rárá. A kò lè rìn kórí má mì nítòótọ́, orí bíbẹ́ kọ́ ni oògùn orí fífọ́ kẹ̀! Ó wu èdùmàrè ló gbórí ẹwà fún àkùkọ, ọ̀pọ̀ igi ló ń bẹ nígbó ká tó fí ìrókò jọba igi.

Ẹ máa jẹ kí á torí ọ̀làjú tàbí òṣèlú gbàgbé àṣà wa. Àṣà ìbọ̀wọ̀ fágbà ni Yorùbá fi ń gbajúmọ̀ nílẹ̀-kílẹ̀. Àgbà kò ní ṣe pẹ̀lú ọjọ́-orí rárá, ipò làgbà.
Àràbà ni bàbá, ẹni a bá lábà ni bàbá. Ọba Adéyeyè lè jẹ́ ọmọdé sùgbọ́n ipò àti àyè tí ó wà gẹ́gẹ́ bí i ỌỌ̀NI ti sọ ọ́ di àràbà tí gbogbo ọba bá lábà. Bí èèyàn bá ta ará ilé ẹ̀ lọ́pọ̀, kò le rí i rà lọ́wọ̀ń.
Bàbá ni Ọọ̀ní jẹ́ láàárín àwọn lọ́ba-lọ́ba. Níwọ̀n ìgbà tí àwọn Ọba tí kìí ṣe Ọba ní ilẹ̀ káàárọ̀-o-jíire lè máa ṣe àpọ́nlé tí ó tọ́ fún Ọọ̀ni, mo lérò pé ó tọ́, ó sì yẹ kí àwọn Ọba yorùbá ṣe àpọ́nlé ara wọn bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ,pàápàá jùlọ fún olórí aládé gbogbo.
Mo kí Ọba Adéyẹyè Ẹnitan Ògúnwùsì, Ọ̀jájá II, kú àíbínú. N kò sàì gbóríyìn fún gbgbo ẹni tó da sí ọ̀rọ̀ náà ní pàtàkì jùlọ Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ GCFR, ààrẹ àná.

Mo rọ́ Ọba Èèko ki ó máa bínú sí Ọọ̀ni lórí ohun tí ó lè fa ìwà àjòjì yìí. Àmọ̀nràn mi ni pé kí Ọba Akiolú ti Èèkó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ọ Ọọ̀ni àti gbogbo ọmọ yorùbá pé òun kò ní dárú asọ bẹ́ẹ̀ sorò mọ.  Lákòtán ọ̀rọ̀ mi, Baba kìí bínú púpọ̀, Kábíèsí, ọba Adéyẹyẹ̀ ẹ fojú fo, bẹ́ẹ̀ ni, ẹ máa gbàgbé ọ̀rọ̀ àwọn Baba ńlá yín pé “Iṣu ẹni níi tọwọ́ ẹnị bepo” kí òwe jẹ́ ti ẹ̀yin àgbà. Kí ẹsin ọba kó joko pẹ́. Ilẹ̀ yorùbá kò ní dàrú o. Àṣẹ.
Tóò bí ó ti mọ ní í jẹ ìrẹ́mọ. Ẹ jẹ kí ẹyin mi di àkùkọ.
Ẹ ṣé púpọ̀.
Ọgbẹ́ni Daniel Adefare
08033234826

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Ọ̀daràn kan fi tipá wọ ààfin Ọ̀ọni ilé ifẹ̀

Ọ̀daràn kan fi tipá wọ ààfin Ọ̀ọni ilé ifẹ̀ A kìí gbélé ẹni ká fi ọrùn rọ́ ni a ti ń gbọ́ tipẹ́ tipẹ́, sùgbọ́n kín wá ni ká ti pe tirúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà yìí tó wáyé ní ààfin Ọọ̀nirìṣà Ọba Adéyẹyè Ògúnwùsì,ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun níbi tí àwọn èèyàn ìlú Ilé Ifẹ̀ ni àwọn ti ń gbọ́ ìró ìbọn ní kíkàn kíkan ní ilé Oòduà tíí ṣe ààfin Ọọ̀nirìṣà Ilé Ifẹ̀, Ọba Adéyẹyè Ògúnwùsì . Eléyìí ló ṣì mú ...