-Sola:. ( O wole, o kumle si egbe ibusun Baba ati Iya re) E jowo, mo nilo owo nile eko ni. Won fun wa ni ise asatilewa kan ni, yoo si na mi to egberun marun naira.
-Baba Sola:. Ha! Egberun marun ke?
-Sola:. Bee ni, baami. Mo ti tu egberun meji jo ninu re pelu oja peepeepe bi eyin tutu, kaadi ipe ati ogede dodo ti mo nta ni yara mi logba. Ojo ti a si fi ise naa sile ti n sun mole. Kigbo’kigba si ni oluko naa.
-Iya Sola:. Iru ise wo ni won wa fun yin yii ti o nilo owo goboi bayii?
-Sola:. Won fun enikookan ni odun ibile ilu kookan pe ki a lo se iwadi re wa. Odun ora ni Ondo ni won si fun mi.
-Iya Sola:. Ha! Ondo lohun’lohun?
-Sola:. Temi tile tun sunmo itile. Awon kan nlo si iyanye ni lpile Goki lohun, Bini wa, koda a ri eni ti o lo si Agbadarigi. Won si ni ki a ya foto bo fun aridaju pe a de ibe.
-Iya Sola:. Lati Ilorin! Eledumare a ma maa fi iso re so yin o.
-Sola:. Ase o. Mo wa ro o pe n o fi gberun kan be aworo odun Ora ti yoo so nnkan fun mi nipa odun naa, won ni Sora lo nje.
-Baba Sola:. Ehen.
-Sola:. N o ra teepu kekere kan ati fonran igbohunsile, keseeti, mo fiyen si egberun kan. Maa fi egberun kan abo si meji wo oko lo ati abo. Eyi to ku, maa ya foto nibe lorisirisi, maa tun mu dani, a ki i mo, inawo miiran ti n ko lero le yoju.
-Iya Sola:. ( O mi kanle) O dara. O kare omo mi. Ori re a kanke. Loro kan sa egberun meta loku ti a nwa?
-Sola:. Beeni, sa.
-Baba Sola:. Igba wo lo fe pada?
-Sola:. Irole ojo ose ni.
-Baba Sola:. Ki Eledumare so wa ju igba naa lo.
-Sola:. Ase , sa. O daaro sa, o daaro ma.
Iya Sola:. Ka sun layo. Oko mi. Okookan la oo ji o. ( Sola jade lo) Ewo wa ni sise bayii? Nibo ni a o ti ri egberun meta lola ode yii?
-Baba Sola:. O su mi o. Omo yii si ti gbiyanju, abi. O ti ri egberun mate ninu marun. Afi ka yaa wa a o. Nitori ki i sabaa ma yo wa lenu nipa owo. O niteelorun pupo.
-Iya sola:. E je ki a gbadura ki oja ya lola. N oo ba alajo mi soro boya o le ya mi ni die kun.
-Baba Sola:. Emi naa a jade, o ye ki le ri die ya. ( Won dubule won sun. O to bii wakati meta si merin leyin eyi ni iya Sola deede taji. O n laagun lakolako. Eru han loju re. O wo yika, o fi owo boju, oju re wale die, o ji oko re pepe)
-Iya Sola:. Baba Sola, baba sola, e dide.
-Baba Sola:.( O n dahun sugbon ko laju. O han pe oorun si n diun mo) Hun’un
-Iya Sola:. ( O sare laju, o wo aago) Se ko si? Aago kan oru ma sese koja ni. ( O yan hoo) kilo de?
-Iya Sola:. E dide jokoo, mo la ala kan ti o bami leru ni.
-Baba Sola:. Ehen, roo ki ngbo.
-Iya Sola:. Mo ri baba kan. Irun re fun’fun balau o si wo aso funfunlatoke dele. O pe Sola, o si gbe ounje aladidun kan le e lowo terinterin. Inu Sola dun gan nitori ebi ti npa gidigidi. Sola wa gbe ouje naa dani, o n gbe wa si odo wa( O nawo si oun ati oko re) Awa naa wa lookan ti a n wo o, inu wa ti n dun nitori ebi ti pa awa naa. Koda, ibi ti ouje naa dara de, gbogbo eniyan ni o n gbooorun tita sansan re.
-Baba Sola:. Ki lo wa sele?
-Iya Sola:. Lojiji ni afa kan bere si fe, o si dabi eni pe Sola ati ouje yii nikan ni o n fe si. O koko dabi itura, bi eni pe ki ooru ma ba a mu ni afefe naa se nfe, ko koko ye gbogbo wa. Nigba to ya, afefe yi di iji lile o si gbe ouje yi kuro lowo Sola sugbon awo na si wa lowo re. Sola wa n sunkun, awa naa wa n sunkun. Ohun to yami lenu nibe ni pe a ko lee ran an lowo. Ori ekun yii la jo wa ti mo fi taji.
-Baba Sola:. Iyen lo wa n lagun si. Ala ma go. Eledumare o ni je ki a rogun ekun lori awon omo wa. Boya oro owo ti a so ka to sun ni o gbe sokan. Eledumare a pese fun wa. Sebi iwo lo maa mu mi lokan le.
-Iya Sola:. Rara, mi o ro pe o ri bi e se nro yen. Itun mo ala yi jinle ju bi e se so yii.
-Baba Sola:. O daa, ki ni ki a wa se bayii? Eledumare yoo daabo re bo gbogbo wa.
-Iya Sola:. Ase ( Awon mejeeji dubule. Ka to seju pe. Kola ti n hanrun sygbon iyawo re ko le sun. Nigba to se die, o kunle o si bere sii gbadura.)
………………….Won daso bo itage………..
Tagged with: Àṣà Yorùbá