Home / Art / Àṣà Oòduà / Osika egbon pa omo aburo re tori owo
aye-akamara

Osika egbon pa omo aburo re tori owo

Ogbeni Samuel Omosaba, eni odun mejilelogoji (42), ni owo awon olopaa ipinle Ondo ti te bayii pelu bo se ge ori omobirin, eni odun meta (3), to je omo aburo re lati fi sogun owo ojiji. Isele yii lo waye ni agboole Ilepa to wa ni Ikare-Akoko ni ijoba ibile Ila-oorun Ariwa Akoko tipinle Ondo.

Ogbeni Omosaba ti ko nise kankan ti n se lo ledi apopo pelu babalawo kan to kale si Ipe-Akoko, eni to seleri lati ba a se ogun owo ojiji to daju to ba le wa ori omode wa.

Omobirin ti won seku pa yii ni iya re, ti n je Bunmi, maa n mu lo sodo iya oko re nigba to ba n lo sibi ise laaaro. Sugbon lojo ti isele buruku yii yoo sele, ko si iya oko re nile, egbon oko re lo ba nile. Egbon oko re naa lo gba omo naa sodo lati toju titi ti iya re yoo fi pada de.

Igba ti iya omo yo pada de, to silekun yara egbon oko re, lo ba oku omo re ti won ti ge ori kuro lorun re. Ogbeni Omosaba pada jewo fun awon ebi nipa bi o se fe fi omo naa gunse owo.

Ogbeni Femi Joseph to je agbenuso fun ile ise olopaa ipinle Ondo ni awon eniyan adugbo naa ko ba ti dana sun Ogbeni Omosaba ti ki i ba ki i se iranlowo awon olopaa. Bakan naa lo tun so wi pe, won ti gbe ejo naa lo si eka ile ise olopaa ti n risi idaran (State Criminal Investigative Department), to wa niluu Akure.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

yoruba

Can we speak Yoruba language without code mixing? is it important?