Home / Art / Àṣà Oòduà / Òtúrá Òfún (Òtúráfùnún)

Òtúrá Òfún (Òtúráfùnún)

Àkúsàba Àyàndà
Awo ilé Olúmẹ̀ri Àápáálá
Ọmọ ilé san wón ó joko lọ
Níjọ́ tí ń ṣọ̀gbọ̀gbọ̀ àrùn
Tí ń najú aláì le dìde
Olúmẹ̀ri Àápáálá làrùn ń ṣe
Òún wá á le gbádùn gbogbo nǹkan òun lójú ayé òun báyìí?
Wọ́n ní ewúrẹ́ kan ni kó rú
Ó rú ewúrẹ́ kan

Wọ́n ṣe Ifá fún un
Wọ́n dá a jẹ ni
Àrùn tí ń ṣe Olúmẹ̀ri ò san
Ótún dìgbà kejì
Ó tún gbókè Ìpọ̀rí rẹ̀ kalẹ̀
Ó tún ní kí Olúmẹ̀ri ó rúbọ
Epo ìgò méjì
Ewúrẹ́ kan
Kée bọ òkè Ìpọ̀rí ẹ̀
Wọ́n tún dá a jẹ

Àrùn tí ń ṣe Olúmẹ̀ri ò san
Olúmẹ̀ri Àápáálá wá á tọ àwọn Aláwo míràn lọ
Àwọn Àáyá dúdú igbó ọ̀dọ́
Àwọn wèrè pupa ọ̀nà ò padà
Àwọn ọ̀tẹ́ẹ́rẹ́ ọ̀tààrà
Ń tí ń ṣàn tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ kó mi lẹgbẹ lẹgbẹ ó tóó dé
Ẹ yẹ òun lọ́wọ́kan ìbò wò!
Wọ́n ní kí Olúmẹ̀ri, rúbọ o
Wọ́n léwúrẹ́ kan lẹbọ
Wọ́n níre fún un

Olúmẹ̀ri Àápáálá lóun ò rú
Lákọ̀ọ́kọ́
Àkúsàba Àyàndà ní kóun ó rú ewúrẹ́ kan
Òún sì ru u
Ohun tí ń ṣe òun ò lọ
Lẹ́ẹ̀kejì
Wọ́n tún ní kóun ó tún rú ewúrẹ́ kan
Àti ìgò epo méjì
Kóun fi bọ òkè Ìpọ̀rí
Ohun tí ń ṣe òun kò san

Wọ́n ní báwo ni wón tí ń ṣe é
Wọ́n ní nígbà àwọn bá ṣè é tán
Làwọn ń jẹ ẹ́
Wọ́n ní háà
Bẹ́ẹ̀ kọ́ọ̀
Wọ́n ní àrùn tí ń ṣe ẹ́ tó kọ̀ tí ò lọ un
Dandan ni kó san
Wọ́n ní ìwọ sá rùú ewúrẹ́ ná
Wọ́n wá á ṣe ọbẹ̀ ewúrẹ́ sílè
Àwọn Babaláwo ò tíì fọwọ́ kàn àn

Wọ́n ní kí wọ́n o yánlẹ̀ sí òkè Ìpọ̀rí Olúmẹ̀ri
Wọ́n bá yánlẹ̀
Wọ́n ní kí wọ́n ó fún baálé
Wọ́n mẹ́ran fún baálé
Wọ́n mẹ́ran fún ìyáálé ilé
Wọ́n ní wón ó fún ọmọ ilé
Wọ́n fún ọmọ ilé
Wọ́n fún ọmọ oṣú
Wọ́n fún kèé bá wọn pé
Wọ́n ní gbogbo ẹni tí ń bẹ lárọ̀ọ́wọ́tó

Wọ́n ní wón ó mọ́ ọn gbé oúnjẹ fún wọn
Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í fún wọn lẹ́ran
Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ tán
Eléyìí ń pé yóò dá a
Tọ̀hún ń pé yóò dá a
Ohun tí ń ṣe Olúmẹ̀ri bá san
‘Ó ní àṣé b’Ifá ò bá r’Awo’
‘Àṣé kò ní jẹun’?
Àṣé nǹkan a mọ́ ọn dá a báyìí?
N ní wá ń jó ní wá ń yọ̀

Ní ń yin àwọn Babaláwo
Àwọn Babaláwo ń yin Ifá
Ó ní bẹ́ẹ̀ làwọn Babaláwo tòun wí
Àkúsàba Àyàndà
Awo ilé Olúmẹ̀ri Àápáálá
Adífá fún Olúmẹ̀ri Àápáálá
Ọmọ ilé san wón ó joko lọ
Níjọ́ tí ń ṣọ̀gbọ̀gbọ̀ àrùn
Tí ń najú aláì le dìde
Ń ṣe ohun gbogbo tí ọ̀kan ò lójú

Ẹbọ ni wọn ó ṣe
Àkúsàba Àyàndà
Ó pewúrẹ́ kìíní
Wọ́n dá a jẹ
N tí ṣe Olúmẹ̀ri ò san
Àkúsàba Àyàndà
Ó pewúrẹ́ kejì
Wọ́n dá a jẹ
Àrùn tí ń ṣe Olúmẹ̀ri ò san
Ó wá á kàwon Àáyá dúdú igbó ọ̀dọ́

Àwọn wèrè pupa ọ̀nà ò padà
Àwon ọ̀tẹ́ẹ́rẹ́ ọ̀tààrà
Ń tí sàn tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ kómi lẹgbẹ lẹgbẹ ó tó ó dé
Wọ́n ní kó pa ewúrẹ́ mìíràn
Kí wọ́n ó há ewúrẹ́ fún gbogbo ará ilé
Wọ́n ó há fárá oko
Èrò tí ń bẹ lọ́nà
Òun náà jẹ́ ńbẹ̀
N tí s’Olúmẹ̀ri wá á san
Àkúsàba Àyàndà
Awo ilé Olúmẹ̀ri Àápáálá
B’Ifá ò bá r’Awo
Kò jẹun

Ifá yóò ma gba ìbọ lọ́wọ́ Awo o!
Àgbàlé ọ̀ṣẹ̀ o!!

Ire ni o!

– Òtúrá Òfún (Òtúráfùnún)m

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti