Home / Art / Àṣà Oòduà / #Our5K ti da wahala sile lori ayelujara: Ile Igbimo Asofin ni wahala naa ti bere
buhari
PIC.29. APC PRESIDENTIAL CANDIDATE, GEN. MUHAMMADU BUHARI (2ND R),PRESENTING HIS RUNNING MATE, PROF. YEMI OSINBAJO TO THE PUBLIC IN ABUJA ON WEDNESDAY (17/12/14).WITH THEM ARE, APC CHAIRMAN, CHIEF JOHN OYEGUN (L) AND THE NATIONAL SECRETARY, ALHAJI MAI-MALA BUNI. 6412/17/12/2014/HF/CH/NAN

#Our5K ti da wahala sile lori ayelujara: Ile Igbimo Asofin ni wahala naa ti bere

#Our5K ti da wahala sile lori ayelujara: Ile Igbimo Asofin ni wahala naa ti bere
Olayemi Olatilewa

Lojo Wesde to koja yii nile igbimo asofin agba to kale siluu Abuja gbegi dina sisan owo egberun marun-un fun awon odo ile Naijiria ti ko nise lowo.

Abadofin eleyii ti asofin Philip Aduda (PDP, FCT) gbe si iwaju ile igbimo lo tile wa tele ninu awon ileri ti Aare Muhammadu Buhari se ni akoko ipolongo idibo re.

Sugbon ohun to jo ni loju ni bi o se je wi pe awon asofin omo egbe APC, ti won je omo egbe kan naa pelu Aare Buhari lo tun wa tako abadofin naa.

Isele to waye naa bere si ni ko awon omo Naijiria lominu, nigba ti opo si gba wi pe ise ti a ran iko niko n je. Ise ti Aare ati egbe APC ran awon asofin re naa ni won musa loogun

Opolopo awon odo ni won tu si ori ero Twitter pelu akori oro #Our5k, ti kaluku won si n so edun okan won pelu bi ijoba Buhari se fe fi ona alumonkoroyi dena ileri to se.

Sugbon sa, akowe ipolongo fun egbe APC, Alaaji Lai Mohammed ni egbe APC ati Aare Buhari ko ni ye nipa ileri re lati san egberun marun-un owo naira fun awon odo ti ko nise lowo.

Gege bi alaye re, o ni alaparutu ni awon omo egbe PDP, ati wi pe awon ni won fe fi oro naa da surutu sile nipa dida ori oro naa kodo.

Lai Mohammed, eni ti won tun ti fonte lu gege bi okan lara awon ti yoo je minisita, so wi pe eto ni gbogbo nnkan. Eniyan gbodo jokoo na ko to nase, ki onitoun ma ba a fipako nale. O ro gbogbo odo wi pe ki won lo mokan bale, gbogbo ileri ti awon se pata ni yoo foju han laipe.

Onwoye nipa oro oselu kan, eni to gba lati ba akoroyin IROYIN OWURO soro lai safihan oruko re, so wi pe, o sowon ninu oloselu ti o mu gbogbo ileri to se ni akoko iponlogo se nikete ti agbara ba de owo re. O ni ki i se ile Naijiria nikan, bo se ri kaakiri agbaye nu-un.

Oloselu a maa so asodun oro ni akoko ipolongo idibo lati ni ero leyin bi oko akoyoyo.

Sugbon pupo ninu ileri won ni agbara won kii ka nigba ti won ba de ori oye. Nigba ti awon kan maa ye iru ileri bee sile ki opo le seku fun igbadun tara won nikan.

 

Orisun: Olayemioniroyin.com

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Àwọ̀ ni Édè Yorùbá

Àwọ̀ ni Édè Yorùbá – Colours in Yoruba Language

Dúdú – BlackÀwọ̀ Ojú Ọ̀run – BlueÀwọ̀ igi – BrownÀwọ̀ Eérú – GrayÀwọ̀ Ewé – GreenÀwọ̀ Òféfèé – OrangePupa – RedFunfun – WhitePupa rusurusu – YellowÀwọ̀ dúdú – Dark colorLight color: Àwọ̀ tí ó mọ́lẹ̀Colors: Àwọn àwọ̀  Ojú Ọ̀run dúdú díẹ̀ – The sky is blueOlógbò rẹ funfun – Your cat is white Àwọ̀ dúdú ní ó yàn láàyò – Black is his favorite colorÀwọ̀ pupa kì íṣe èyí tí ó yàn láàyò – Red is not his favorite colorÓ nwà ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ...