Home / Art / Àṣà Oòduà / Owó te olùsó àgùntàn(pastor) èké kan nígbà tí ó ń gbìyànjú láti ri ohun tí a kò mò sí ilé onílé. 
pasito

Owó te olùsó àgùntàn(pastor) èké kan nígbà tí ó ń gbìyànjú láti ri ohun tí a kò mò sí ilé onílé. 

Olùsó àgùntàn èké kan tí a mò sí Osinachi Christopher láti ìpínlè Abia ni won fi s’èsín léyìn ìgbà tí owó ti tèé nígbà tí ó ń gbìyànjú à ti ri ohun tí a kò mò sí ilé onílé ní agbègbè Nnobi ní ìpínlè Anambra . Gégé bí eni tí ó pin se so èyí kó ni àkókó tí Olùsó àgùntàn náà ma se èyí.

Ka ohun tí Uzochukwu Onuabuchi so ní ojó etì tí ó kojá, ojó ketàlélógún osù kefà (Friday, June 23rd)

Ojú kò kú ní yé rí, ìyanu kò sì le dópin .Olùsó àgùntàn Osinachi Christopher rè é láti Isuochi ní ìpínlè Anambra,  owó tè é nígbà tí ó fé ri ohun tí a kò mò sí ilé onílé, tí won ma padà gbé jáde l’órúko ìdílé náà, ó tún jéwó wípé sisé pèlú Olùsó àgùntàn kan tí orúko rè ńjé Miracle Ihuoma.

Ó tún jéwó wípé. Olùsó àgùntàn èké Miracle ri ohun tí a kò mò sí iwájú ìsò Alabi kan tí ó jé ìyàwó Makosa. Olùsó àgùntàn yí tún wá so fún arabìnrin yí wípé Olùsó àgùntàn ti télè Ebubedike ni ó ri ohun náà síbè. Ònà èké yí ni ó gbà láti lé Ebubedike lo. Ebubedike tí olórun ti ń lò fún isé ìyanu ní Nnobi.

Ohun kan tí èmi mò láyé ni pé kò sí ohun tí ó pamó lábé òrun. Olórun ti fi Olùsó àgùntàn èké Miracle Ihuoma hàn , tí ó ní Ìjo ní Makosa ní Ifite Nnobi ní ìpínlè Anambra.

Gégé bí Olùsó àgùntàn èké Osinachi nínú àwòrán àti Miracle Ihuoma. Ó seoooooo ……

Continue after the page break for English version

About ayangalu

VI

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

policeman

Ọ̀gbẹ́ni Olaoye déèdé pòórá nílé ìtura kan nílùú Akure

Fẹ́mi Akínṣọlá Ádùrá tí a máa ń ṣe ni pé kí á má rin àrin f’ẹsẹ̀sí.Mọ̀lẹ́bí ọkùnrin kan, Ògbẹ́ni Olaoye Olatunde, tó jẹ́ igbákejì ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ girama kan nílùú Ọwọ ti ké gbàjarè pé ọkùnrin náà di àwárítì lẹ́yìn tó lọ fún idanilẹkọ ní ilé ìtura Sunview nílùú Akure. Iyawo arakunrin naa salaye rẹ pe, ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ, ọdun 2025, ni ọkọ rẹ dagbere pe ohun n lọ fun idanilekọ kan n’iluu Akure, eyi ti wọn ...