Èro àlọ, Ẹ wá gbọ́, èrò àbọ̀, Ẹ wá tẹ́tí sími
Oògùn ọlá tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ní mo fẹ́ wí f’áyé
Oògùn ọrọ̀ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ní mo fẹ́ ròyìn
Àtọjọ́ mo ti dáyé, Àtọjọ́ mo ti ń ṣiṣẹ́
Àtòjọ mo ti ń dààmú sáré kiri
Èmi ò mọ̀ pé oògùn ọlá kan wà tóju ká fi ọṣẹ forí lọ
Àní pé òògùn ọ̀rọ̀ kan wa tójú àwúre lọ
Mo ti kékeré lọ si Sokoto torí kí nlè lówó lọ́wọ́
Mo dàgbà tán gba Calabar lọ kí ń lè l’ọ́là lágbàlá
Mo dé Saki, dé Iseyin nítorí kí n lè l’ọrọ̀ léyìnkùnlé
Èmi ò mọ̀ pé ohun tí mo ń wá lọ Sokoto
Wà ní àpò Ṣòkòtò bùbá mi
Mo ti f’ọsẹ fọ́rí-fọrí, síbẹ̀ mi ò lówó lọ́wọ́
Ọ̀pọ̀ àsèjẹ ni mo ti komì, síbẹ̀ mi ò là
Ọ̀pọ̀ àbẹ́là ni mo ti tàn mọ́jú, síbẹ̀ mi ò rí t’ajé se
Hàntú ti mo mu kò l’òńkà, síbẹ̀ mi o ni láárí
Kàkà kó sàn lára mi, níṣe lo tún le koko si
Gbogbo ewúrẹ́ ilé mi ni me e rúbọ ọlá tán
Gbogbo àgùntàn ọ̀dẹ̀dẹ̀ mi ni me e se ètùtù ọlà
Mo fi gbogbo pẹ́péyẹ àgbàlá mi gúnsẹ àwúre
Mo kó gbogbo ẹyẹlé òrùlé mi fi s’àsèje ọrọ̀
Síbẹ̀ n ò rọ́wọ́ fi họrí, n ò rí ọwọ́ mu lọ ètè
Àwọn Alálùfáà gbowó titi, ko si ìyàtọ̀
Babaláwo gba ewure fa a, síbẹ̀ Ifá ò fọ re
Adáhunse gba agutan bẹ́ẹ̀ ko sí ayípadà rere kan
Ọlọ́sanyìn gba otí ìbílẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ naa òlójùtùú
Ọ̀kẹ́ àìmọye òróró Àdúrà ni mo rà fún wòlíì
Síbẹ̀síbẹ̀ ko sí àyípadà rere
Mo ba bẹ̀rẹ̀ sí bẹ orí, pe ko sọmí dolówó
Mo pe ìṣẹ̀dá mi níjà pé ko gbà mí kalẹ̀ lọ́wọ́ òsì
Orí gbọ́, orí gbémi pàdé oògùn owó tó dájú
Ìṣẹ̀dá gbà ó fi mi sọ̀rẹ́ oògùn ọrọ̀ ti ko lábàwọ́n
Oògùn owó ti mò n wí ò gba ewúrẹ́
Oògùn ọrọ̀ ti mò ń sọ ò gba àgùntàn
Oògùn ajé tí mo fẹ́ ròyìn kò gbẹ̀jẹ́
Oògùn owó ti mo fẹ́ wi lómú adé gbayì láàrin fìlà
Ohun lómú káún d’ọ̀gá láwùjọ òkútà
Lómú Iyọ̀ gbayì láwùjọ erùpẹ̀
Ọ̀YÀYÀ lorúkọ oògùn òhún n jẹ́
Olùtajà tó ní ọ̀yàyà ní rí owó kójọ
Oníṣẹ́ ọwọ́ tó ní ọ̀yàyà ní ń rí iṣẹ́ gbà
Òṣìṣẹ́ ìjọba tó ní ọ̀yàyà Irú wọn kìí pẹ́ gbokùn lẹ́nu isẹ́
Ọmọ ilé-Ìwé tó ní ọ̀yàyà ló n gbọ́ ohun olùkọ́ sọ yé
Ọmọ ìkọ́ṣẹ́ tó ní ọ̀yàyà, irú wọ́n lọ̀gá ń fi iṣẹ́ hàn
Ọmọge tó ń ṣe ọ̀yàyà, irú wọn ni ń ri ọkọ gidi fẹ
Ọ̀dọ́mọkùrin tó l’ọ̀yàyà lobìnrin ń dù
Ìyàwó ilé to l’ọ́yàyà, lọkọ ń fẹ́ràn
Ẹni a ṣe ọ̀yàyà sí lónìí, a tún padà wá lọ́lá
Ọ̀dájú kò ní wá lásán torí bó délé yóó ròyìn fún tẹrú tọmọ
L’èèyàn bá di aníyì káyé, olókìkí káàkiri
Iwúrí kíni ń bẹ níbi ki èèyàn fajúro?
Èrè wo ló ń bẹ nínú ká di ẹnu kukuku?
Aní owó wó là ń rígbà níbi kí èèyàn dijú mórí?
Ọlá wo ló ń bẹ nínú odì yíyàn?
Iyì wo lówà lára òsónú ẹ̀dá?
Ọ̀rẹ́ mi, ye e súré ka, ye dààmú kiri
Àní o yé fi èèyàn gúnsẹ nítorí owó
Ye fi ènìyàn jó oògùn nítorí ọlà
Ye to jú bọ ilé Adahúnse, onísègùn, wòlíì pẹ̀lú Àlùfáà fún ọsẹ àwúre
Ọ̀yàyà ni kí o gbìnyànjú kí o ni
Ọ̀yàyà ni kí o gbìnyànjú kí o yan láàyò.
Yé fi oògùn ẹ̀tẹ́ wo làpálàpá
Ọ̀yàyà ní oògùn àti ọ̀nà àbáyọ si ọ̀rọ̀ rẹ