Home / Art / Àṣà Oòduà / Rántí òla

Rántí òla

Ohun tí a se lónìí
Ìtàn ni b’ódòla
Lisabi Agbongbo Àkàlà
Fi ìwà akin gba gbogbo Ègbá kalè
L’óko erú Olóòyó

Ògèdèngbé ń be nínú ìwé ìtàn ìjeshà
Asíwájú rere ní se

Moremi obìnrinkùnrin n’ífè ńkó, a kò le gbàgbé rè láéláé

Efunroye Tinubu l’égbàá ilé ńkó, obìnrin ogun tí Ó so àwon òyìnbó d’òdè

Ipa tí won kó fún ìdàgbàsókè ìlú won
Ló so wón di olókìkí

Òkìkí irú èwo ni ìwo fé ní
Ò ń be l’éwe
Okúrò ní màjèsí
Ìwà àfowórá erù elérù
Kò kúrò lówó rè
O dàgbà tán
Èékán ni o tún je

Nínú àwon kò nísé àdúgbó
Àwon egbé re ni màjèsí tepámósé
Olúsisé ìná kò tówó
Ni won se ń rí ajé jeun

Olówó yí tè mí mólè ko kojá lo se ń bùkèlè ní tìre
Àgbà lò ń dà yí
Sé iró lo fé kí omó jogún ni
Àbí Ìwà àfowórá erù elérù tí o fi ńlé se ara rin-in-din
Yára rántí òla
Rántí òla, àgbà lò ń dà yí
Yára rántí òla, jáwó nínú àpòn tí kò yò, dá omi ilá ka ná
Kí òrò re má bà di akútúkú eni ibi tí o bá re ibi àgbà ńlé rè.

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti