O ti wa daju wi pe kosi oun ti okunrin se ti obirin o le se. Bi eniyan ba si foju kere ata, afaimo ki iru eni bee ma kabamo leyin oro. Eni Edua Oke ba fe ni i fun logbon gidi. Eni to ba wu Oluwa Oba ni i dalola koja oye eda. Bi eniyan ba dite eni Oosa oke gbe soke, o daju wi pe ebi lonitoun yoo pada je.
Lori asayan oro yii ni i ti maa safihan Simisola Omoayan, ogbontarigi omidan ti n fi kongo ilu pidan. Orekelewa amuludun ti n fopolo sise akin. Sebi o wu Edumare lo se ori ewa fakuko. O wu oba adaniwaye lo jogun ogbon ilu lilu fun Titilola Omoayan.
Gege bi iwadii Olayemi Oniroyin, ajogunba ni ilu lilu je fun Simisola Omoayan. Kosi si ilu naa ti won fawo yi loju ti Simisola ko le topa ilu bo loju. Sugbon o feran ilu gangan ni lilu ju awon ilu yoku lo. Odun yii ni Simisola kawe gboye akoko ninu ise alakada logba Ifafiti ti ipinle Ekiti. Awon ojogbon ti won ko ni kilaasi si jeri si i wi pe, bi omo naa se logbon iwe bee lo tun mede ayan lojulowo.
Boya eyin ko tile mo, aimoye awon agbaoje ni Simisola ti ba tayo ise opolo bi Lagbaja omo baba mukomuko. Bakan naa, ojo ti Simisola Omoayan pade Ayanbirin, ojo naa ni gbogbo eniyan mo wi pe ebun nla pamo sinu Omoayan.
Olayemi Oniroyin, maa duro nibi naa kaye to so pe temi po. Amo sa, ohun to daju ni wi pe mi o ni rise opolo to joju ki n gbe won pamo. Emi o ni reni to lebun to wayami ki n wa fenu tembelu iru won. Laye n bi ko, emi o ni ba won daru re lasa.