Orisun
Awon omo egbe onimoto NURTW eka ti ijoba ibile Owo to kale si ipinle Ondo buta sira won loju lojo Isegun to koja yii.
Awon iko meji kan ti won je ti egbe NURTW la gbo wi pe won ja si ipo alaga eleyii lo sokunfa ija nla ti aimoye awon eniyan si farapa yannayanna.
Ija yii lo bere ni agbegbe ile itura First Molac titi to fi de opopona Ehinogbe to wa niluu Owo. Nibi ti awon omo onimoto naa ti n yinbo kikankikan bi eni wi pe ogun abele lo be sile ni agbegbe naa. Eni ori yo, o dile. Aimoye oloja lo salo lai duro gbe oja won lorita.
Gege bi iwadii Iroyin Owuro, okunrin kan ti inagije re n je “Jungunnu” la gbo wi pe o sadeede kede ara re gege bi alaga egbe onimoto agbegbe naa.
Jungunnu ko awon omo eyin re lati lo na siamaanu egbe naa, Ogbeni Kolade Jasper mo ofiisi re to wa ni ibudoko Akure, legbe ile itura First Molac. Oro naa ko ba bo sori patapata, opelope awon olopaa kogberegbe ti won sare jigiri si isele naa.
Nibayii, Ogbeni Kolade ni oun si ni siamaanu egbe naa fun ti eka ilu Owo. O tun fi kun un wi pe Jungunnu ki i se omo egbe awako rara. Ko si sohun to mu leto gege si ipo alaga egbe onimoto.
Alarinna fun ile ise olopaa ipinle Ondo, Ogbeni Femi Joseph, je ri si isele to waye naa. O si fi da awon ara ilu loju wi pe ile ise olopaa n se gbogbo akitiyan lati ri daju wi pe alaafia joba ni agbegbe ilu Owo.