Arakunrin Amamgbo ni asiri re tu lori ise iwadii ti ajo naa n se lati mo gbogbo ibi ti Alison-Madueke fara pamo si lori awon owo ilu to koje nigba to wa nipo gege bi minisita epo robi.
Ogbeni Amamgbo la gbo wi pe o n lo awon ile ise okoowo epo robi bi merin kan, eleyii ti oruko re han lori awon ile ise naa gege alakoso, lati gbon epo robi ile wa lo si awon ilu okeere.
Awon ile ise ti ajo EFCC kede re wi pe Ogbeni Amamgbo n lo ni Mezcor Oil and Gas Limited, Tridax Oil and Gas Limited, Lynear Energy Limited ati Bulk Strategic Reserve Limited.
Okan ninu awon ile ise naa to kale si agbegbe Wuse to wa niluu Abuja ni ajo EFCC ti tipa bayii raurau. Gege bi iwadii OLAYEMI ONIROYIN, lara awon iwe ti won riko ninu ile ise naa ni awon iwe ti won fi ra ile aimoye ati ogunlogo oko bogini olowo iyebiye.
Gege bi alaye ajo EFCC, won ni orisiirisii ona ni Madueke n lo lati fi se ise ibi. Aimoye ona lo si ti fi kowo ilu mi bi kalokalo ni oruko awon ebi ati ojulumo re.
Lowolowo bayii, awon osise ti n gbogun ti iwa idaran ni ilu London naa ko dake lori awon iwadii won lori esun kiko owo ilu je ti won fi kan Madueke. Lati inu osu kewaa odun to koja ni won si ti fi ofin de Madueke lati ma jade lo si ibikibi.
Pada sori alaye ajo EFCC, ojo ti n ro ti ko ti i da ni esun iwa jegudujera ti won fi kan Alison-Madueke, Edua oke nikan lo moye eni to seku ti o pa.