O kere tan awon eniyan bi meji ni won gborun lo ni Ikare-Akoko to wa ni ipinle Ondo nigba ti awon eniyan bi mewaa farapa koja bikiafu nibi ija to wayii laaarin awon omo onimoto.
Wahala to bere lati nnkan bi ago meje aaro putu Ojobo to koja yii ni awon ganfe kan ti gbe yawo Ikare-Akoko pelu ada, obe, igo ati bajinatu elenu sagila ti won si bere si ni se ijamba lorisiirisii ni agbegbe naa.
Gege bi alaye to te Olayemi Oniroyin lowo se so, ohun ti awon omo yada-yobe naa wi ni wi pe, siamaanu NURTW eka ti Ikare-Akoko to ti n je tele naa ni yoo tun ma je lo. Itaporogan naa to ti mu emi dani, eleyii to tun fi opolopo dukia sofo ni ko ba bo sori patapata ti ki i ba se iranlowo awon olopaa digboluja ti won sare bomi pana rugudu naa.
Oga olopaa, DPO to di agbegbe Ikare-Akoko mu, Ogbeni Musiliu Sogbade jeri si isele to waye naa. Bakan naa ni won fi da awon ara ilu loju wi pe alaafia ti pada si agbegbe naa latari iranlowo awon agbofinro.
Orisun: Olayemioniroyin.com