Home / Art / Àṣà Oòduà / A Dúró Lójú Òpó Ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Àkọ́kọ́ Lórí Ẹjọ́ Ajimobi – Adájọ́
Abiola Ajimobi

A Dúró Lójú Òpó Ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Àkọ́kọ́ Lórí Ẹjọ́ Ajimobi – Adájọ́

A dúró lójú òpó ìdájọ́ ilé Ẹjọ́ àkọ́kọ́ lórí ẹjọ́ Ajimobi – Adájọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà àná ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Abiola Ajimọbi ti fìdí rẹmi nínú ìpẹ̀jọ́ rẹ̀ láti tako ìbò tí ó gbé ojúgbà rẹ̀ Kọla Balogun wọlé gẹ́gẹ́ bíi Sẹ́nétọ̀.
Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ni ó fagilé ìwé ìpẹ̀jọ́ tí Ajimọbi fi pe sẹ́nétọ̀ náà tí ó ń ṣojú gúúsù Ìpínlẹ̀ náà lẹ́jọ́.


Ṣe lórí ìdìbò ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kejì ọdún yìí tí Balogun ní ìbò 105,720 nígbà tí Ajimọbi ní 92,218.
Nígbà tí ó ń dá ẹjọ́ náà, Justice Haruna Tsammani ni ó da ìpẹ̀jọ́ náà nù tí ó ní kò lẹ́sẹ̀ ń lẹ̀ rárá.
Adájọ́ náà ni ó wá gùn lé ìgbẹ́jọ́ ilé ẹjọ́ tí ó rí sí èsì ìbò pé ìdájọ́ òdodo ni wọ́n ti kọ́kọ́ dá.


Ilé ẹjọ́ sọ pé Ajimọbi kò ní àṣẹ láti sọ wí pé Balogun kò tọ̀nà láti díje lábẹ́ àṣìá ẹgbẹ́ òsèlú PDP. Ó ní, ẹni tí kò kópa nínú ètò ìbò abẹ́lé kò ní àṣẹ láti tako ìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ òsèlú kankan.


Adájọ́ náà tẹ̀síwájú pé, kété tí ajọ tí ó ń rí sí ètò ìbò àti ẹgbẹ́ òsèlú bá ti fọwọ́ sí ẹnikẹ́ni pé ó gbéwọ̀n, kò sí ìdádúró mọ́ fúnrúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀.
Tsammani wá wí pé gbogbo ẹ̀rí tí Ajimọbi kó kalẹ̀ kò lẹ́sẹ̀ ń lẹ rárá láti tàbùkù alátakò rẹ̀.
Ó kásẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nílẹ̀ pé, ilé ẹjọ́ ṣe ìdájọ́ tó yẹ bí wọ́n ṣe dá Sínátọ̀ Kola Balogun láre.

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

dapo abiodun

Dapo Abiodun: Ogun State Has Highest Number Of Yahoo Yahoo Boys

The Ogun State Government has admitted that it parades highest number of internet fraudsters known as yahoo yahoo boys in the country, with declaration that it is determined to stop the menace. Penpushing reports that, Governor Dapo Abiodun made the disclosure on Friday while speaking at launch of ‘OP-MESA’, a joint security outfit, explaining that the reasons behind the rate was the existence of high number of institutions in the state. The Governor explained that, in view of this, his ...