Iroyin Lati Ọwọ Olayemi Olatilewa
Gomina Rauf Aregbesola tipinle Osun ti lo si ileewe girama, Olufi Middle School to kale si Gbongan ni Ijoba Ibile Ayedaade to wa nipinle naa. Nibi ayeye ti won ti n si ileewe naa ni Ogbeni Aregbesola ti n so wi pe, Aadoje milionu (N130m) owo naira ile wa lo pari ileewe naa, a ti wi pe yiya ni awon ya owo naa.
Nibi ayeye naa ni gomina ti n ro awon oluko ati awon alase ileewe naa lati se itoju ileewe naa daada, eleyii to fi je wi pe ki atunse kankan to tun le waye nibe yo to nnkan bi aadota (50) odun sigba taa wa yii.
Ogbeni Aregbesola ti awon kan tun mo si Baba Kabiru lo tun se apejuwe ara re nibi ayeye naa gege bi ojise Olorun, eni ti a ran lati wa so igba derun fun gbogbo mekunnu pata. O se lalaye ninu oro re wi pe, iru agbekale ati ara ti won fi ileewe naa da fe e je eyi ti enikeni ko le ri nibikibi lagbaye nitori ara oto ni.
Ogbeni Aregbe tun se lalaye siwaju wi pe, awon ileewe girama bi mokanla (11) ni ijoba oun ti ko. Bakan naa lo si seleri wi pe awon ileewe girama bi meje (7) ni oun yoo ko ninu odun 2016.
“Awon ileewe alakobere bi ogorun (100) lo wa ninu ipinnu wa lati ko, a si ti ko bi meedogun (15) ninu won bayii. Bakan naa, ni agbara Olorun, ileewe girama bi aadota (50) ni yoo di kiko ni ipinle Osun,” Aregbe se lalaye bee.
Aregbe ko tun sai soro lori ipo ailera ti eto oro-aje ile Naijiria wa bayii. O si so wi pe, akurete to ti de ba eto oro-aje ti se aimoye akoba fun awon eto ijoba si ara ilu, eleyii to si je edun okan nla fun un.
O wa n fi asiko naa ro awon odo lati jigiri si ise agbe ni sise lojulowo.
“Ipo ti a ba ara wa bayii gege bi orileede, ise agbe nikan lo le ran wa lowo. Idi ni yii ti a fi n ro awon odo wa lati mu ise agbe lokunkundun ki n kan le pada senure fun wa ni Naijiria,” Aregbe fi kun alaye re bee