Home / Art / Àṣà Oòduà / Niluu Ilorin: “Awon osise mefa ti ku, awon kan wa nile iwosan”- Akowe egbe osise
Abdulfatah Ahmed

Niluu Ilorin: “Awon osise mefa ti ku, awon kan wa nile iwosan”- Akowe egbe osise

Awon osise ajo olomi ti ipinle Kwara tu jade lojo Isegun to koja yii niluu Ilorin nigba ti won fi ehonu won han nipa owo osu won eleyii ti ijoba ipinle naa ko lati san lati inu osu keje seyin.

Olayemi Olatilewa

Yato si owo osu won, awon owo ajemonu kan naa tun wa lati ibere odun yii ti a gbo wi pe awon osise naa n beere lowo ijoba eleyii to je wi pe bakan naa lomo se sori pelu owo osu ti won o ri gba. Eleyii to tun se eleeketa iru e ni awon osise to ye ki won ti ni igbega lati inu odun 2012 sugbon ti igbega naa ko waye.

 

Awon osise ajo olomi ipinle naa ni won gbarajo labe egbe kan ti nje Amalgamated Union of Public Corporations, Civil Service Technical and Recreational Services Employees (AUPCTRE), eleyii to je ti eka ajo olomi ti ipinle Kwara.

Awon osise yii ni won gbegi dina geeti abawole to wa leka ile ise ijoba naa nigba ti won fi ehonu won han eleyii to waye fun aimoye wakati.

Nibi ifehonu han naa ti n waye ni ati ri awon osise kan ti won gbe orisiirisii akole dani eleyii ti die nibe wi pe: “E san owo osu wa o”, E fun wa leto wa”, E ma foju gongosu wo wa, awa o go o”; “Ti eyin ba ni e ko ni sanwo, awa gan-an o ni sise”.

Gege bi olori egbe osise eka ti ajo olomi ipinle Kwara, Ogbeni  Murtala se so. “Aimoye leta ni ati ko si awon alase pelu ijoba sugbon to je wi pe ibi pelebe naa ni awon abebe ti a n ju soke naa fin in lele nigbogbo igba. Awa osise ti gbiyanju oun ti a mo, igba ti won sun wa kangiri la tu jade”.

Gege bi oro Ogbeni Murtala, o ni ki i se wi pe idunnu awon lo je bi awon se duro sinu oorun lai lounje ninu, sugbon ni kete ti ijoba ba ti dawon lohun awon nnkan ti awon beere fun dandan ni ki awon pada senu ise lai fi akoko sofo.

Akowe egbe osise, Ogbeni Saliu Sulaiman naa ko sai so ero tie naa fun awon oniroyin. O ni isoro ti awon ni ni wi pe ijoba o ka won kun rara.

A tile gbo wi pe awon osise yii fun ijoba ipinle naa ni gbedeke ojo merinla lati dahun awon ibeere won saaju ki ifehonuhan naa to waye. Sugbon ojo merinla naa ti koja eleyii to fa bi gbogbo osise naa se tu yaaya soju popona bi ero Mecca.

Gege bi afikun oro enu akowe naa, o ni awon osise bi mefa ni won ti padanu emi won bayii nigba ti awon kan wa nile iwosan latari wi pe won ko ri owo toju ara won botito ati botiye.

“Pupo ninu awon osise ajo olomi lo je wi pe ese ni won rin wa sibi ise nijoojumo latari wi pe ko sowo lapo won ti won le fi wo moto akero. Bakan naa ni won ti le awon kan kuro nile latari wi pe won o ri owo ile san fun awon onile won”.

Leyin isele to waye yii  ni oluranlowo agba fun gomina ipinle Kwara nipa eto iroyin, Dr Muyideen Akorede fida awon oniroyin loju wi pe ijoba yoo sa gbogbo ipa ati agbara re lati pase ohun ti awon osise naa n beere fun, ti alaafia yoo si pada joba.

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti