Home / Art / Àṣà Oòduà / Won je David Mark, Amaechi ati Fasola lenu bi obi abata
David Mark

Won je David Mark, Amaechi ati Fasola lenu bi obi abata

Orisun
Oniroyin Twitter

Won je David Mark, Amaechi ati Fasola lenu bi obi abata
*Didake David Mark n ko awon eniyan lominu
*Asa tuntun ti won da:
“Mi o gba riba ri laye mi” – Amaechi
“Gege bi gomina, mi o saini seeki ri ”- Fasola
Oniroyin: Olayemi Olatilewa

David Mark
Awon omo Naijiria ti bere si ni kominu pelu didake ti aare ile igbimo asofin agba ana, David Mark, se ko ti o soro tabi dasi awon oro to n lo nile igbimo asofin gege bi omo ile. Paapa julo, didake re ni akoko ti awon ile igbimo asofin agba n se iforowanilenuwo fun awon minisita ti Aare Buhari fi oruko won ranse.

Gege bi omo ile igbimo to ni iriri julo, opolopo awon omo Naijiria ni won reti idasi re ninu awon oro to se koko sugbon ti maanu naa ko ti o soro lati igba ti won ti gbe ile igbimo eleekejo to wa lode yii ro.

Igba marun-un otooto ni won ti dibo yan David Mark, eni odun metadinlaadorin (67), sile igbimo asofin agba Abuja. Ninu eto idibo odun 1999, 2003, 2007, 2011 ati ti 2015 to waye laipe yii, David Mark naa ni igba funfun re n leke omi lati soju Guusu Benue nile igbimo asofin ti won ti n fi aga alaso pupa jokoo.

Yato si wi pe o ni anfaani lati jawe olubori nipa jije omo ile igbimo lodun 2011, Mark to ti fi igba kan je alakoso ipinle Niger lodun 1984 si 1986 ninu isejoba ologun, tun pada jawe olubori gege bi aare ile igbimo asofin agba eleyii to jokoo laaarin 2011 si 2015. Akoko yii si fe e je igba ti okiki re kan julo ninu oselu ile Naijiria.

Opolopo awon eniyan ni won ti lero wi pe baba naa o lo sinmi nile nigba to ba pari ise re gege bi aare ile igbimo asofin agba. Sugbon ninu eto idibo odun 2015, odoodun ni sapo n ruwe ni David Mark fi oro naa se pelu bo se pada wa gege bi omo ile igbimo asofin fun igba karun-un.

David Mark ko di ipo agbara kankan mu nile igbimo asofin eleekejo iru e to wa lode yii, bakan naa ni iriri re gege bi asofin to pe ju lo nile igbimo farasin ni awon akoko tile ba pade.

Awon onwoye lagbo oselu ati awon onimo nipa irori eda eniyan gba wi pe didake ogbeni Mark le je latari bi pupo awon omo leyin re nigba kan se di ipo asaaju mu nile igbimo oteyii, nigba ti oun bi enikan to n ti je oga wa pada di omo leyin to kan an jokoo lori aga lasan lai ni irawo kankan lapa.

Lara afikun awon onwoye tun ni wi pe, o le je boya o n gbiyanju lati fi ara re si ipo owo (aponle) nipa didake ti n dake roro bi omi inu amu. Se e mo wi pe awon ijiroro lori awon abadofin ile igbimo kii waye laisi ariwo pipa mora eni, riranju mora eni, eleyii to tun maa la gidigbo lo Iawon igba mi-in. O le je awon ohun to n sa fun ni yii to fi n sebi abata takete bi eni wi pe ko bodo tan-an tabi ko je wi pe ojuti ni o je o soro.

O jo bi eni wi pe awon ara ilu gan-an ko tile kobiara si bi ogbeni David Mark ko se ki n dasi awon oro to n lo nile igbimo asofin. Sugbon ohun to pe akiyesi awon eniyan ko ju bi kamera ile ise telifisan kan se gbe aworan Mark jade nibi to pelengo si legbe kan , to si n wo bi eni wi pe ohun ti n lo ko kan-an rara. Eleyii waye nigba ti ile n da ibeere orisiirisii bo Rotimi Amaechi, okan lara awon minisita ti won fi oruko won ranse.

E jeri awon omo Naija, kete ti won foju ri Mark ni iye won so. Ti won si se bee fo fere sori ero iwiregbe Twitter nibi won ti n tu gbogbo oun to ha won lona ofun da sile. Die ni yii lara awon oro to n lo lori ayelujara nipa asofin David Mark.

Musbau Bolaji: [@Bonjila] Onworan le mi kaa si. Ohun to si maa n sele seeyan niyi nigba o ba ti pe lori imi.

Aisha: [@aisha_modibbo] Maanu naa le maa dake latari wi pe oju n ti, ko si mo bo se fe pe Bukola Saraki ni “Mr Senate President sir”.

AS Aruwa [@Musadiqz] David Mark, agbalagba ana, wa di eni ti n wo bi omode ti won gba pofupoofu re lonii. Sio.

Abu Hashim [@zvyyd] E dakun sir, oga Bukola Saraki, bi o tile je adura ibere ati ipari, e je ki David Mark naa ma se.

IG:Osi.lama: [Osi_lama] Emi ko tile kofiri baba naa rara. Se e suo wi pe David Mark mbe nile igbimo sa?

fashola

Raji Fasola

Alade: [@alade80] Ti omo ile iwe ba ti ripiiti kilaasi, ki lo tu ku ju ko ma wo bi ori eran lo.

Yato si oro David Mark ti n ja raninranin lori ero iwiregbe Twitter, awon omo Naija tun ti bere si ni dasa tuntun eleyii to jeyo latari awon idahun Raji Fasola ati Rotimi Amaechi ti won je gomina tele fun ipinle Eko ati Rivers leseese.

Rotimi Amaechi

Rotimi Amaechi

Ni akoko ti ile igbimo asofin agba n fi oro wa Fasola lenu wo, won beere nipa milionu mejidinlogorin (N78M) to na sori ikanni adani re lori ayelujara, www.fashola.com. Fasola ni ko si owo ti oun na ni akoko oun gege bi gomina ipinle Eko eleyii ti ko gba ona to ye jade.
“Gege bi gomina, mi o saini seeki ri”- Fasola.
Iru ipade yii na jade ninu idahun Rotimi Amaechi, eni to si ni awon esun kan ti won fi ko o lorun nipa isowo ilu mokumoku. Lara awon idahun Amaechi niwaju ile igbimo asofin ni , “Emi o gba riba ri laye mi”.

“Gege bi gomina, mi o saini seeki ri”, “Mi o gba riba ri laye mi”, ti di asa nla bayii eleyii ti opolopo awon eniyan naa ti bere si ni so ohun ti awon ko se ri.

Arabirin kan ti awon ojulumo re n pe ni mama Bolu ni oun o sun mo okunrin ri laye oun. Awon omo ile iwe kan ni awon o jiwe wo ri laye awon. Nigba ti awon kan ni awon o bu tisa leyin ri. Okunrin kan ti oruko re n je Saheed, to pe ara re ni mekaliiki naa dasi oro naa,“ gege bi mekaliiki, mi o fowo kan epo enjinni oko ri laye mi”.

 

Orisun
Oniroyin Twitter

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

taniolohun

Esin Ajeji Pelu Ete